Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Samuẹli Kinni 1:3-17 BIBELI MIMỌ (BM)

3. Ní ọdọọdún ni Elikana máa ń ti Ramataimu-sofimu lọ sí Ṣilo láti lọ sin OLUWA àwọn ọmọ ogun, ati láti rúbọ sí i. Hofini ati Finehasi, àwọn ọmọ Eli, ni alufaa OLUWA níbẹ̀.

4. Ní ọjọ́ tí Elikana bá rú ẹbọ rẹ̀, a máa fún Penina ní ìdá kan ninu nǹkan tí ó bá fi rúbọ, a sì máa fún àwọn ọmọ rẹ̀ lọkunrin ati lobinrin ní ìdá kọ̀ọ̀kan.

5. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó fẹ́ràn Hana, sibẹ ìdá kan ní í máa ń fún un, nítorí pé OLUWA kò fún un ní ọmọ bí.

6. Penina, orogún Hana, a máa fín in níràn gidigidi, kí ó baà lè mú un bínú, nítorí pé OLUWA kò fún un ní ọmọ bí.

7. Ní ọdọọdún tí wọ́n bá ti lọ sí ilé OLUWA ni Penina máa ń mú Hana bínú tóbẹ́ẹ̀ tí Hana fi máa ń sọkún, tí kò sì ní jẹun.

8. Ọkọ rẹ̀ a máa rẹ̀ ẹ́ lẹ́kún, a máa bi í pé, “Kí ní ń pa ọ́ lẹ́kún? Kí ló dé tí o kò jẹun? Kí ní ń bà ọ́ lọ́kàn jẹ́? Ṣé n kò wá ju ọmọ mẹ́wàá lọ fún ọ ni?”

9. Ní ọjọ́ kan, lẹ́yìn tí wọ́n jẹ, tí wọ́n mu tán, ninu ilé OLUWA, ní Ṣilo, Hana dìde. Eli, alufaa wà ní ìjókòó lórí àpótí, lẹ́bàá òpó ẹnu ọ̀nà ilé OLUWA.

10. Inú Hana bàjẹ́ gan-an, ó bẹ̀rẹ̀ sí gbadura sí OLUWA, ó sì ń sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn.

11. Hana bá OLUWA jẹ́jẹ̀ẹ́ ó ní, “OLUWA àwọn ọmọ ogun, bí o bá ṣíjú wo ìyà tí èmi iranṣẹ rẹ ń jẹ, tí o kò gbàgbé mi, tí o fún mi ní ọmọkunrin kan, n óo ya ọmọ náà sọ́tọ̀ fún ìwọ OLUWA ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀, abẹ kò sì ní kàn án lórí.”

12. Bí Hana ti ń gbadura sí OLUWA, Eli ń wo ẹnu rẹ̀.

13. Hana ń gbadura ninu ọkàn rẹ̀, kìkì ètè rẹ̀ nìkan ní ń mì, ẹnikẹ́ni kò gbọ́ ohun tí ó ń sọ. Nítorí náà, Eli rò pé ó ti mu ọtí yó ni.

14. Ó bá bẹ̀rẹ̀ sí bá a wí pé, “O óo ti mu ọtí waini pẹ́ tó? Sinmi ọtí mímu.”

15. Hana dá a lóhùn, pé, “Rárá o, oluwa mi, n kò fẹnu kan ọtí waini tabi ọtí líle. Ìbànújẹ́ ló bá mi, tóbẹ́ẹ̀ tí mo fi ń gbadura, tí mo sì ń tú ọkàn mi jáde fún OLUWA.

16. Má rò pé ọ̀kan ninu àwọn oníranù obinrin ni mí. Ninu ìbànújẹ́ ńlá ati àníyàn ni mò ń gbadura yìí.”

17. Eli bá dá a lóhùn, ó ní, “Máa lọ ní alaafia, Ọlọrun Israẹli yóo fún ọ ní ohun tí ò ń tọrọ lọ́wọ́ rẹ̀.”

Ka pipe ipin Samuẹli Kinni 1