Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Samuẹli Kinni 1:12-20 BIBELI MIMỌ (BM)

12. Bí Hana ti ń gbadura sí OLUWA, Eli ń wo ẹnu rẹ̀.

13. Hana ń gbadura ninu ọkàn rẹ̀, kìkì ètè rẹ̀ nìkan ní ń mì, ẹnikẹ́ni kò gbọ́ ohun tí ó ń sọ. Nítorí náà, Eli rò pé ó ti mu ọtí yó ni.

14. Ó bá bẹ̀rẹ̀ sí bá a wí pé, “O óo ti mu ọtí waini pẹ́ tó? Sinmi ọtí mímu.”

15. Hana dá a lóhùn, pé, “Rárá o, oluwa mi, n kò fẹnu kan ọtí waini tabi ọtí líle. Ìbànújẹ́ ló bá mi, tóbẹ́ẹ̀ tí mo fi ń gbadura, tí mo sì ń tú ọkàn mi jáde fún OLUWA.

16. Má rò pé ọ̀kan ninu àwọn oníranù obinrin ni mí. Ninu ìbànújẹ́ ńlá ati àníyàn ni mò ń gbadura yìí.”

17. Eli bá dá a lóhùn, ó ní, “Máa lọ ní alaafia, Ọlọrun Israẹli yóo fún ọ ní ohun tí ò ń tọrọ lọ́wọ́ rẹ̀.”

18. Hana bá dá a lóhùn pé, “Jẹ́ kí èmi, iranṣẹbinrin rẹ, bá ojurere rẹ pàdé.” Ó bá dìde, ó jẹun, ó dárayá, kò sì banújẹ́ mọ́.

19. Ní òwúrọ̀ kutukutu ọjọ́ keji, Elikana ati ìdílé rẹ̀ múra, wọ́n sì sin OLUWA. Lẹ́yìn náà, wọ́n gbéra, wọ́n pada sí ilé wọn, ní Rama. Nígbà tí ó yá, Elikana bá Hana lòpọ̀, OLUWA sì gbọ́ adura rẹ̀.

20. Hana lóyún, ó bí ọmọkunrin kan, ó sọ ọmọ náà ní Samuẹli, ó ní, “Títọrọ ni mo tọrọ rẹ̀ lọ́wọ́ OLUWA.”

Ka pipe ipin Samuẹli Kinni 1