Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Samuẹli Keji 6:1-12 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Dafidi tún pe gbogbo àwọn akikanju ninu àwọn ọmọ ogun Israẹli jọ; wọ́n jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ati ẹgbaarun (30,000).

2. Ó kó wọn lọ sí Baala ní Juda láti gbé àpótí ẹ̀rí Ọlọrun wá sí Jerusalẹmu. Orúkọ OLUWA àwọn ọmọ ogun ni wọ́n fi ń pe àpótí ẹ̀rí náà, ìtẹ́ rẹ̀ sì wà lórí àwọn Kerubu tí ó wà lókè àpótí náà.

3. Wọ́n gbé àpótí ẹ̀rí jáde kúrò ní ilé Abinadabu tí ó wà lórí òkè, wọ́n sì gbé e ka orí kẹ̀kẹ́ tuntun kan. Usa ati Ahio ọmọ Abinadabu sì ń ti kẹ̀kẹ́ náà;

4. Ahio ni ó ṣáájú rẹ̀.

5. Dafidi ati gbogbo àwọn ọmọ Israẹli bẹ̀rẹ̀ sí jó níwájú OLUWA, wọ́n sì ń kọrin pẹlu gbogbo agbára wọn. Wọ́n ń lu àwọn ohun èlò orin olókùn tí wọ́n ń pè ní hapu, ati lire; ati ìlù, ati ṣẹ̀kẹ̀rẹ̀ ati aro.

6. Bí wọ́n ti dé ibi ìpakà Nakoni, àwọn mààlúù tí ń fa kẹ̀kẹ́ tí àpótí ẹ̀rí wà lórí rẹ̀ kọsẹ̀, Usa bá yára di àpótí ẹ̀rí náà mú.

7. Inú bí OLUWA sí Usa, OLUWA sì lù ú pa nítorí pé ó fi ọwọ́ kan àpótí ẹ̀rí náà. Usa kú sẹ́gbẹ̀ẹ́ àpótí ẹ̀rí náà.

8. Inú bí Dafidi gidigidi nítorí pé OLUWA lu Usa pa. Láti ìgbà náà ni wọ́n ti ń pe ibẹ̀ ní Peresi Usa, títí di òní olónìí.

9. Ẹ̀rù OLUWA ba Dafidi ní ọjọ́ náà, ó sì wí pé, “Báwo ni n óo ṣe gbé àpótí ẹ̀rí OLUWA wá sọ́dọ̀ mi?”

10. Ọkàn rẹ̀ bá yipada, ó pinnu pé òun kò ní gbé e lọ sí Jerusalẹmu, ìlú Dafidi mọ́. Dípò bẹ́ẹ̀, ó gbé e lọ sí ilé Obedi Edomu, ará ìlú Gati.

11. Àpótí ẹ̀rí OLUWA náà wà níbẹ̀ fún oṣù mẹta, OLUWA sì bukun Obedi Edomu ati ìdílé rẹ̀.

12. Wọ́n bá lọ sọ fún Dafidi pé, “OLUWA ti bukun Obedi Edomu, ati gbogbo ohun tí ó ní, nítorí pé àpótí ẹ̀rí OLUWA wà ní ilé rẹ̀.” Dafidi bá lọ gbé àpótí ẹ̀rí náà kúrò ní ilé rẹ̀ wá sí Jerusalẹmu, pẹlu àjọyọ̀ ńlá.

Ka pipe ipin Samuẹli Keji 6