Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Samuẹli Keji 5:1-8 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Lẹ́yìn náà, gbogbo àwọn ẹ̀yà Israẹli tọ Dafidi lọ ní Heburoni, wọ́n sọ fún un pé, “Ara kan náà ni wá, ẹ̀jẹ̀ kan náà sì ni gbogbo wa.

2. Látẹ̀yìn wá, nígbà tí Saulu pàápàá wà lórí oyè, ìwọ ni o máa ń kó àwọn ọmọ Israẹli lọ sógun. OLUWA sì ti ṣèlérí fún ọ pé, ìwọ ni o óo jẹ́ aṣiwaju àwọn eniyan rẹ̀, ati ọba wọn.”

3. Gbogbo àwọn àgbààgbà Israẹli wá sí ọ̀dọ̀ ọba ní Heburoni, Dafidi ọba sì bá wọn dá majẹmu níbẹ̀ níwájú OLUWA. Wọ́n bá fi òróró yan Dafidi ní ọba lórí Israẹli.

4. Ẹni ọgbọ̀n ọdún ni, nígbà tí ó gorí oyè, ó sì jọba fún ogoji ọdún.

5. Ọdún meje ati oṣù mẹfa ni ó fi jọba lórí ẹ̀yà Juda ní Heburoni. Lẹ́yìn náà, ó wá sí Jerusalẹmu ó sì jọba lórí gbogbo Israẹli ati Juda fún ọdún mẹtalelọgbọn.

6. Nígbà tí ó yá, Dafidi ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀ gbógun ti ìlú Jerusalẹmu. Àwọn ará Jebusi tí wọn ń gbé ibẹ̀ nígbà náà wí fún Dafidi pé, “O kò lè wọ inú ìlú yìí wá, àwọn afọ́jú ati àwọn arọ lásán ti tó láti lé ọ dànù.” Wọ́n lérò pé Dafidi kò le ṣẹgun ìlú náà.

7. Ṣugbọn Dafidi jagun gba Sioni, ìlú olódi wọn. Sioni sì di ibi tí wọn ń pè ní ìlú Dafidi.

8. Dafidi bá sọ fún àwọn eniyan rẹ̀ ní ọjọ́ náà pé, “Jẹ́ kí ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ pa àwọn ará Jebusi gba ojú àgbàrá lọ pa àwọn afọ́jú ati àwọn arọ tí ọkàn Dafidi kórìíra.” (Ìdí nìyí tí wọ́n fi ń wí pé, “Àwọn afọ́jú ati àwọn arọ kò ní lè wọ ilé OLUWA.”)

Ka pipe ipin Samuẹli Keji 5