Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Samuẹli Keji 3:12-26 BIBELI MIMỌ (BM)

12. Abineri bá ranṣẹ sí Dafidi ní Heburoni pé, “Ṣebí ìwọ ni o ni ilẹ̀ yìí? Bá mi dá majẹmu, n óo wà lẹ́yìn rẹ, n óo sì mú kí gbogbo Israẹli pada sọ́dọ̀ rẹ.”

13. Dafidi bá dáhùn pé, “Ó dára, n óo bá ọ dá majẹmu. Ṣugbọn nǹkankan ni mo fẹ́ kí o ṣe, o kò ní fi ojú kàn mí, àfi bí o bá mú Mikali ọmọbinrin Saulu lọ́wọ́ nígbà tí o bá ń bọ̀ wá rí mi.”

14. Dafidi bá rán àwọn oníṣẹ́ kan sí Iṣiboṣẹti, ọmọ Saulu, pé kí ó dá Mikali, aya òun, tí òun san ọgọrun-un awọ orí adọ̀dọ́ àwọn ará Filistia lé lórí pada fún òun.

15. Iṣiboṣẹti bá ranṣẹ lọ gba Mikali lọ́wọ́ Palitieli, ọmọ Laiṣi, ọkọ rẹ̀.

16. Ṣugbọn bí ó ti ń lọ ni ọkọ rẹ̀ ń sọkún tẹ̀lé e títí tí ó fi dé Bahurimu, ibẹ̀ ni Abineri ti dá a pada, ó sì pada.

17. Abineri tọ àwọn àgbààgbà Israẹli lọ, ó ní, “Ó pẹ́ tí ẹ ti fẹ́ kí Dafidi jẹ́ ọba yín.

18. Àkókò nìyí láti ṣe ohun tí ẹ ti fẹ́ ṣe, nítorí pé OLUWA ti ṣe ìlérí fún Dafidi pé Dafidi ni òun óo lò láti gba àwọn ọmọ Israẹli kúrò lọ́wọ́ àwọn ará Filistia ati gbogbo àwọn ọ̀tá wọn yòókù.”

19. Abineri bá àwọn ará Bẹnjamini sọ̀rọ̀ pẹlu. Lẹ́yìn náà ó lọ bá Dafidi ní Heburoni láti sọ ohun tí àwọn ará Bẹnjamini ati gbogbo ọmọ Israẹli ti gbà láti ṣe fún Dafidi.

20. Nígbà tí Abineri dé ọ̀dọ̀ Dafidi ní Heburoni pẹlu ogún ọkunrin tí ń bá a lọ, Dafidi se àsè ńlá fún wọn.

21. Abineri bá sọ fún Dafidi pé, “N óo lọ, n óo wá ọ̀nà tí gbogbo Israẹli yóo fi wà lẹ́yìn rẹ, oluwa mi, (ọba), tí wọn yóo bá ọ dá majẹmu tí o óo sì jọba lórí gbogbo ibi tí ọkàn rẹ bá fẹ́.” Dafidi ní kí ó máa lọ, ó sì lọ ní alaafia.

22. Kò pẹ́ pupọ lẹ́yìn náà, ni Joabu ati àwọn ọmọ ogun Dafidi pada dé láti ibi tí wọ́n ti lọ ja ogun kan, wọ́n sì kó ọpọlọpọ ìkógun bọ̀. Ṣugbọn Abineri kò sí lọ́dọ̀ Dafidi, ní Heburoni, nígbà tí wọ́n dé, nítorí pé Dafidi ti ní kí ó máa pada lọ, ó sì ti lọ ní alaafia.

23. Nígbà tí Joabu ati àwọn ọmọ ogun tí wọ́n tẹ̀lé e dé, wọ́n sọ fún Joabu pé, “Abineri ti wá sí ọ̀dọ̀ Dafidi ọba, ọba sì ti jẹ́ kí ó lọ ní alaafia.”

24. Joabu bá lọ sí ọ̀dọ̀ ọba, ó bèèrè pé, “Irú kí ni o ṣe yìí, Abineri wá sí ọ̀dọ̀ rẹ, o sì jẹ́ kí ó lọ bẹ́ẹ̀?

25. Ṣebí o mọ̀ pé ó wá tàn ọ́ jẹ ni? Ó wá fi ọgbọ́n wádìí gbogbo ibi tí ò ń lọ, ati gbogbo ohun tí ò ń ṣe ni.”

26. Nígbà tí Joabu kúrò lọ́dọ̀ Dafidi, ó ranṣẹ lọ pe Abineri, wọ́n sì dá a pada láti ibi kànga Sira, ṣugbọn Dafidi kò mọ nǹkankan nípa rẹ̀.

Ka pipe ipin Samuẹli Keji 3