Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Samuẹli Keji 21:1-4 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ní àkókò ìjọba Dafidi, ìyàn ńlá kan mú, fún odidi ọdún mẹta. Dafidi bá lọ wádìí ọ̀rọ̀ náà lọ́dọ̀ OLUWA. OLUWA sì dáhùn pé, “Saulu ati ìdílé rẹ̀ jẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ ìpànìyàn, nítorí pé ó pa àwọn ará Gibeoni.”

2. Àwọn ará Gibeoni kì í ṣe ara àwọn ọmọ Israẹli. Ara àwọn ará Amori tí wọ́n ṣẹ́kù ni wọ́n. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọmọ Israẹli ti ṣèlérí pé àwọn kò ní pa wọ́n, sibẹsibẹ Saulu gbìyànjú láti pa wọ́n run, nítorí ìtara rẹ̀ fún àwọn ọmọ Israẹli ati Juda.

3. Dafidi bá pe àwọn ará Gibeoni, ó sì bi wọ́n pé, “Kí ni ẹ fẹ́ kí n ṣe fun yín? Ọ̀nà wo ni mo lè gbà ṣe àtúnṣe ibi tí wọ́n ṣe si yín, kí ẹ baà lè súre fún àwọn eniyan OLUWA?”

4. Wọ́n dá a lóhùn pé, “Aáwọ̀ tí ó wà láàrin àwa ati Saulu ati ìdílé rẹ̀, kì í ṣe ohun tí a lè fi wúrà ati fadaka parí, a kò sì fẹ́ pa ẹnikẹ́ni ninu àwọn ọmọ Israẹli.”Dafidi bá tún bèèrè pé, “Kí ni ẹ wá fẹ́ kí n ṣe fun yín?”

Ka pipe ipin Samuẹli Keji 21