Àwọn ará Gibeoni kì í ṣe ara àwọn ọmọ Israẹli. Ara àwọn ará Amori tí wọ́n ṣẹ́kù ni wọ́n. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọmọ Israẹli ti ṣèlérí pé àwọn kò ní pa wọ́n, sibẹsibẹ Saulu gbìyànjú láti pa wọ́n run, nítorí ìtara rẹ̀ fún àwọn ọmọ Israẹli ati Juda.