Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Samuẹli Keji 18:10-30 BIBELI MIMỌ (BM)

10. Ọ̀kan ninu àwọn ọmọ ogun Dafidi rí i, ó bá lọ sọ fún Joabu pé òun rí Absalomu tí ó ń rọ̀ lórí igi Oaku.

11. Joabu dá a lóhùn pé, “Nígbà tí o rí i, kí ló dé tí o kò pa á níbẹ̀ lẹsẹkẹsẹ? Inú mi ìbá dùn láti fún ọ ní owó fadaka mẹ́wàá ati ìgbànú akikanju ninu ogun jíjà.”

12. Ṣugbọn ọmọ ogun náà dáhùn pé, “Ò báà tilẹ̀ fún mi ní ẹgbẹrun (1,000) owó fadaka, n kò ní ṣíwọ́ sókè pa ọmọ ọba. Gbogbo wa ni a gbọ́, nígbà tí ọba pàṣẹ fún ìwọ ati Abiṣai ati Itai pé, nítorí ti òun ọba, kí ẹ má pa Absalomu lára.

13. Tí mo bá ṣe àìgbọràn sí òfin ọba, tí mo sì pa Absalomu, ó pẹ́ ni, ó yá ni, ọba yóo gbọ́, bí ọba bá sì gbọ́, ìwọ gan-an kò ní gbà mí sílẹ̀.”

14. Joabu dáhùn pé, “N kò ní máa fi àkókò mi ṣòfò, kí n sọ pé mò ń bá ọ sọ̀rọ̀.” Joabu bá mú ọ̀kọ̀ mẹta, ó sọ wọ́n lu Absalomu ní igbá àyà lórí igi oaku tí ó há sí.

15. Mẹ́wàá ninu àwọn ọdọmọkunrin tí wọn ń ru ihamọra Joabu bá yí Absalomu po, wọ́n sì ṣá a pa.

16. Lẹ́yìn náà, Joabu fọn fèrè ogun, kí wọ́n dáwọ́ ogun jíjà dúró. Àwọn ọmọ ogun Dafidi bá pada lẹ́yìn àwọn ọmọ ogun Israẹli.

17. Wọ́n gbé òkú Absalomu jù sinu ihò jíjìn kan ninu igbó, wọ́n sì kó ọpọlọpọ òkúta jọ sórí òkú rẹ̀. Gbogbo àwọn ọmọ ogun Israẹli bá sá, olukuluku gba ilé rẹ̀ lọ.

18. Nígbà ayé Absalomu, ó ṣe ọ̀wọ̀n ìrántí kan fún ara rẹ̀ ní àfonífojì ọba, nítorí kò ní ọmọkunrin kankan tí ó le gbé orúkọ rẹ̀ ró. Nítorí náà ni ó ṣe sọ ọ̀wọ̀n náà ní orúkọ ara rẹ̀; ọ̀wọ̀n Absalomu ni wọ́n ń pe ọ̀wọ̀n náà, títí di òní olónìí.

19. Ahimaasi, ọmọ Sadoku bá sọ fún Joabu pé, “Jẹ́ kí n sáré tọ ọba lọ, kí n sì fún un ní ìròyìn ayọ̀ náà, pé OLUWA ti gbà á lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá rẹ̀.”

20. Ṣugbọn Joabu dá a lóhùn pé, “Rárá o, kì í ṣe ìwọ ni o óo mú ìròyìn náà lọ lónìí, bí ó bá di ọjọ́ mìíràn, o lè mú ìròyìn ayọ̀ lọ. Kì í ṣe òní, nítorí pé ọmọ ọba ni ó kú.”

21. Joabu bá sọ fún ọ̀kan ninu àwọn ará Kuṣi pé, “Lọ sọ ohun tí o rí fún ọba.” Ará Kuṣi náà bá tẹríba fún Joabu, ó sì sáré lọ.

22. Ṣugbọn Ahimaasi ṣá tẹnu mọ́ ọn pé, “N kò kọ ohunkohun tí ó lè ṣẹlẹ̀, jọ̀wọ́ jẹ́ kí n sáré tẹ̀lé ará Kuṣi náà lọ.”Joabu bi í pé, “Kí ló dé tí o fi fẹ́ lọ, ọmọ mi? Kò sí èrè kankan fún ọ níbẹ̀.”

23. Ahimaasi dáhùn pé, “Mo ṣá fẹ́ lọ ni, ohun yòówù tí ó lè ṣẹlẹ̀.”Joabu dáhùn pé, “Ǹjẹ́ bí o bá fẹ́, máa lọ.” Ahimaasi bá sáré gba ọ̀nà pẹ̀tẹ́lẹ̀ lọ, ó sì ṣáájú ará Kuṣi náà.

24. Dafidi wà ní àlàfo tí ó wà ní ààrin ẹnu ọ̀nà tinú ati ti òde, ní ẹnu ibodè ìlú. Ẹ̀ṣọ́ tí ń ṣọ́ bodè gun orí odi lọ, ó dúró lé orí òrùlé ẹnubodè. Bí ó ṣe gbé ojú sókè, ó rí ẹyọ ẹnìkan ṣoṣo tí ó ń sáré bọ̀.

25. Ó pe ọba nísàlẹ̀, ó sì sọ fún un, ọba bá dáhùn pé, “Bí ó bá jẹ́ òun nìkan ni, ìròyìn ayọ̀ ni ó ń mú bọ̀.” Ẹni tí ń sáré bọ̀ náà túbọ̀ ń súnmọ́ tòsí.

26. Ẹ̀ṣọ́ náà tún rí ẹyọ ẹnìkan, tí òun náà ń sáré bọ̀. Ó tún ké sí ẹ̀ṣọ́ tí ó wà ní ẹnu ọ̀nà, ó ní, “Wò ó, ẹnìkan ni ó tún ń sáré bọ̀ yìí.”Ọba dáhùn pé, “Ìròyìn ayọ̀ ni òun náà ń mú bọ̀.”

27. Ẹ̀ṣọ́ tún ní, “Ẹni tí ó ṣáájú tí mo rí yìí jọ Ahimaasi.”Ọba dáhùn pé, “Eniyan dáradára ni, ìròyìn ayọ̀ ni ó sì ń mú bọ̀.”

28. Ahimaasi bá kígbe sókè pé, “Alaafia ni!” Ó wólẹ̀, ó dojúbolẹ̀ níwájú ọba, ó sì wí fún un pé, “Ìyìn ni fún OLUWA Ọlọrun rẹ tí ó fún ọ ní ìṣẹ́gun lórí àwọn tí wọ́n dìtẹ̀ mọ́ ọba, oluwa mi.”

29. Ọba bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Ṣé nǹkankan kò ṣe Absalomu ọmọ mi?”Ahimaasi dá ọba lóhùn pé, “Kabiyesi, nígbà tí Joabu fi ń rán mi bọ̀, gbogbo nǹkan dàrú, ó sì rí rúdurùdu, nítorí náà n kò lè sọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ gan-an.”

30. Ọba bá ní kí ó dúró ní ẹ̀gbẹ́ kan ná, ó bá dúró.

Ka pipe ipin Samuẹli Keji 18