Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Samuẹli Keji 17:2-16 BIBELI MIMỌ (BM)

2. N óo kọlù ú nígbà tí àárẹ̀ bá mú un; tí ọkàn rẹ̀ sì rẹ̀wẹ̀sì; ẹ̀rù yóo bà á, gbogbo àwọn eniyan rẹ̀ yóo sì sá lọ. Ọba nìkan ṣoṣo ni n óo pa.

3. N óo sì kó gbogbo àwọn eniyan rẹ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ, gẹ́gẹ́ bí iyawo tí ó lọ bá ọkọ rẹ̀ nílé. Ẹyọ ẹnìkan ṣoṣo ni o fẹ́ pa, àwọn eniyan yòókù yóo sì wà ní alaafia.”

4. Ìmọ̀ràn náà dára lójú Absalomu ati gbogbo àgbààgbà Israẹli.

5. Ṣugbọn Absalomu dáhùn pé, “Ẹ pe Huṣai wá, kí á gbọ́ ohun tí òun náà yóo sọ.”

6. Nígbà tí Huṣai dé, Absalomu wí fún un pé, “Ìmọ̀ràn tí Ahitofeli fún wa nìyí, ṣé kí á tẹ̀lé e? Bí kò bá yẹ kí á tẹ̀lé e, sọ ohun tí ó yẹ kí á ṣe fún wa.”

7. Huṣai dáhùn pé, “Ìmọ̀ràn tí Ahitofeli fún Kabiyesi ní àkókò yìí, kò dára.

8. Ṣebí o mọ̀ pé, akikanju jagunjagun ni baba rẹ, ati àwọn eniyan tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀? Ara kan wọ́n báyìí, wọn yóo sì rorò ju abo ẹkùn beari tí ọdẹ jí lọ́mọ kó lọ. Bẹ́ẹ̀ sì ni jagunjagun tí ó ní ọpọlọpọ ìrírí ni baba rẹ, kò sì ní sùn lọ́dọ̀ àwọn eniyan rẹ̀ ní alẹ́ yìí.

9. Bóyá bí a ti ń sọ̀rọ̀ yìí, ninu ihò ilẹ̀ níbìkan ni ó wà tabi ibòmíràn. Bí Dafidi bá kọlu àwọn eniyan rẹ, tí wọ́n sì pa díẹ̀ ninu wọn, àwọn tí wọ́n bá gbọ́ yóo wí pé wọ́n ti ṣẹgun àwọn eniyan Absalomu.

10. Nígbà náà, ẹ̀rù yóo ba àwọn tí wọ́n jẹ́ akikanju jùlọ ninu àwọn eniyan rẹ, tí wọ́n sì láyà bíi kinniun; nítorí pé, gbogbo eniyan ní Israẹli ni ó mọ̀ pé akọni jagunjagun ni baba rẹ, akikanju sì ni àwọn eniyan tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀.

11. Ìmọ̀ràn tèmi ni pé kí o kó gbogbo àwọn ọmọ ogun jọ jákèjádò ilẹ̀ Israẹli láti Dani títí dé Beeriṣeba, kí wọ́n pọ̀ bíi yanrìn etí òkun. Ìwọ gan-an ni kí o ṣáájú wọn lọ sí ogun náà.

12. A óo kọlu Dafidi níbikíbi tí a bá ti bá a, a óo bò wọ́n bí ìgbà tí ìrì bá sẹ̀ sórí ilẹ̀; ẹnikẹ́ni kò sì ní yè ninu òun ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀.

13. Bí ó bá sá wọ inú ìlú kan, àwọn ọmọ Israẹli yóo fi okùn fa ìlú náà lulẹ̀ sinu àfonífojì tí ó wà ní ìsàlẹ̀. Ẹyọ òkúta kan ṣoṣo kò ní ṣẹ́kù sórí òkè náà.”

14. Absalomu ati gbogbo Israẹli dáhùn pé, “Ìmọ̀ràn ti Huṣai dára ju ti Ahitofeli lọ,” nítorí pé OLUWA ti pinnu láti yí ìmọ̀ràn rere tí Ahitofeli mú wá pada, kí ibi lè bá Absalomu.

15. Huṣai bá lọ sọ fún Sadoku ati Abiatari, àwọn alufaa mejeeji, irú ìmọ̀ràn tí Ahitofeli fún Absalomu ati àwọn ọmọ Israẹli, ati èyí tí òun fún wọn.

16. Huṣai tún fi kún un pé, kí wọ́n ranṣẹ kíákíá lọ sọ fún Dafidi pé, kò gbọdọ̀ sùn níbi tí wọ́n ti ń ré odò Jọdani kọjá ninu aṣálẹ̀ ní òru ọjọ́ náà. Ó gbọdọ̀ kọjá sí òdìkejì odò lẹsẹkẹsẹ kí ọwọ́ má baà tẹ̀ ẹ́ ati àwọn eniyan tí wọ́n wà lọ́dọ̀ rẹ̀, kí wọ́n sì pa wọ́n.

Ka pipe ipin Samuẹli Keji 17