Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Samuẹli Keji 16:1-13 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ní gẹ́rẹ́ tí Dafidi kọjá góńgó orí òkè náà, Siba, iranṣẹ Mẹfiboṣẹti pàdé rẹ̀, ó ń da àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ bíi mélòó kan bọ̀ tí ó di igba (200) burẹdi rù, pẹlu ọgọrun-un ṣiiri èso resini, ati ọgọrun-un ṣiiri èso tútù mìíràn ati àpò aláwọ kan tí ó kún fún ọtí waini.

2. Dafidi ọba bi í pé, “Kí ni o fẹ́ fi gbogbo nǹkan wọnyi ṣe?”Siba dá a lóhùn pé, “Mo mú àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọnyi wá kí àwọn ìdílé Kabiyesi lè rí nǹkan gùn, mo mú burẹdi, ati èso wọnyi wá kí àwọn ọdọmọkunrin tí wọ́n wà pẹlu rẹ lè rí nǹkan jẹ; ati ọtí waini, kí àwọn tí àárẹ̀ bá mú ninu aṣálẹ̀ lè rí nǹkan mu.”

3. Ọba tún bi í pé, “Níbo ni Mẹfiboṣẹti, ọmọ ọmọ Saulu, ọ̀gá rẹ wà?”Siba dá a lóhùn pé, “Mẹfiboṣẹti dúró sí Jerusalẹmu; nítorí ó dá a lójú pé, nisinsinyii ni àwọn ọmọ Israẹli yóo dá ìjọba Saulu baba-baba rẹ̀ pada fún un.”

4. Ọba bá sọ fún Siba pé, “Gbogbo ohun tí ó jẹ́ ti Mẹfiboṣẹti di tìrẹ láti ìsinsìnyìí lọ.”Siba sọ fún ọba pé, “Kabiyesi, mo júbà, jọ̀wọ́, jẹ́ kí n máa bá ojurere rẹ pàdé nígbà gbogbo.”

5. Nígbà tí Dafidi ọba dé Bahurimu, ọkunrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ṣimei, ọmọ Gera, láti inú ìdílé Saulu, jáde sí i, bí ó sì ti ń bọ̀, bẹ́ẹ̀ ni ó ń ṣépè lemọ́lemọ́.

6. Ó ń sọ òkúta lu Dafidi ati gbogbo àwọn iranṣẹ rẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn eniyan ńláńlá ati ọpọlọpọ eniyan mìíràn wà ní ẹ̀gbẹ́ kinni keji Dafidi ọba.

7. Ṣimei ń wí fún Dafidi bí ó ti ń ṣépè pé, “Kúrò lọ́dọ̀ mi! Kúrò lọ́dọ̀ mi! Ìwọ apànìyàn ati eniyan lásán!

8. Ìwọ tí o gba ìjọba mọ́ Saulu lọ́wọ́, OLUWA ń jẹ ọ́ níyà nisinsinyii, fún ọpọlọpọ eniyan tí o pa ninu ìdílé Saulu. OLUWA sì ti fi ìjọba rẹ fún Absalomu, ọmọ rẹ, ìparun ti dé bá ọ, nítorí pé apànìyàn ni ọ́.”

9. Abiṣai, ọmọ Seruaya wí fún ọba pé, “Kí ló dé tí òkú ajá lásánlàsàn yìí fi ń ṣépè lé ọba, oluwa mi? Jẹ́ kí n lọ sọ́dọ̀ rẹ̀, kí n sì sọ orí rẹ̀ kalẹ̀ kúrò ní ọrùn rẹ̀.”

10. Ṣugbọn ọba dáhùn pé, “Kò sí ohun tí ó kan ẹ̀yin ọmọ Seruaya ninu ọ̀rọ̀ yìí. Kí ni n óo ti ṣe yín sí, ẹ̀yin ọmọ Seruaya? Bí ó bá jẹ́ pé OLUWA ni ó sọ fún un pé kí ó máa ṣépè lé mi, ta ló ní ẹ̀tọ́ láti bèèrè pé, kí ló dé tí ó fi ń ṣe bẹ́ẹ̀?”

11. Dafidi sọ fún Abiṣai ati àwọn iranṣẹ rẹ̀ pé, “Ṣebí ọmọ tèmi gan-an ni ó ń gbìyànjú láti pa mí yìí, kí ló dé tí ọ̀rọ̀ ti ará Bẹnjamini yìí fi wá jọ yín lójú. OLUWA ni ó ní kí ó máa ṣépè, nítorí náà, ẹ fi sílẹ̀, ẹ jẹ́ kí ó máa ṣẹ́ ẹ.

12. Bóyá OLUWA lè wo ìpọ́njú mi, kí ó sì fi ìre dípò èpè tí ó ń ṣẹ́ lé mi.”

13. Dafidi ati àwọn eniyan rẹ̀ bá ń bá tiwọn lọ, Ṣimei sì ń tẹ̀lé wọn lẹ́gbẹ̀ẹ́ keji òkè náà, bí ó ti ń tẹ̀lé wọn, bẹ́ẹ̀ ni ó ń ṣépè, ó ń sọ òkúta lù ú, ó sì ń da erùpẹ̀ sí wọn lára.

Ka pipe ipin Samuẹli Keji 16