Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Samuẹli Keji 14:19-28 BIBELI MIMỌ (BM)

19. Ọba bá bí i pé, “Ṣé Joabu ni ó rán ọ ní gbogbo iṣẹ́ tí o wá jẹ́ yìí, àbí òun kọ?”Obinrin náà dáhùn pé, “Kabiyesi, bí o ti bèèrè ìbéèrè yìí kò jẹ́ kí n mọ̀ bí mo ti lè yí ẹnu pada rárá. Òtítọ́ ni, Joabu ni ó kọ́ mi ní gbogbo ohun tí mo sọ, ati gbogbo bí mo ti ṣe.

20. Ṣugbọn, òun náà fẹ́ tún nǹkan ṣe, ni ó fi ṣe ohun tí ó ṣe. Ṣugbọn kabiyesi ní ọgbọ́n bí angẹli Ọlọ́run, láti mọ ohun gbogbo lórí ilẹ̀ ayé.”

21. Nígbà náà ni ọba sọ fún Joabu pé, “Mo ti pinnu láti ṣe ohun tí o fẹ́ kí n ṣe. Lọ, kí o sì mú Absalomu, ọmọ mi, pada wá.”

22. Joabu bá wólẹ̀, ó dojúbolẹ̀, ó sì dúpẹ́ lọ́wọ́ ọba, ó ní, “Kabiyesi, nisinsinyii ni èmi iranṣẹ rẹ mọ̀ pé mo ti bá ojurere rẹ pàdé, nítorí pé o ṣe ohun tí mo fẹ́.”

23. Joabu bá gbéra, ó lọ sí Geṣuri, ó sì mú Absalomu pada wá sí Jerusalẹmu.

24. Ṣugbọn ọba pàṣẹ pé kí Absalomu máa gbé ilé rẹ̀, nítorí pé òun kò fẹ́ rí i sójú. Nítorí náà, inú ilé Absalomu ni ó ń gbé, kò sì dé ọ̀dọ̀ ọba rárá.

25. Kò sí ẹyọ ẹnìkan ní gbogbo Israẹli tí òkìkí ẹwà rẹ̀ kàn bí ti Absalomu. Kò sí àbùkù kankan rárá lára rẹ̀ bí ti í wù kó mọ, láti orí títí dé àtẹ́lẹsẹ̀ rẹ̀.

26. Ẹ̀ẹ̀kan lọ́dún ni í máa ń gé irun orí rẹ̀, nígbà tí ó bá kún, tí ó sì gùn ju bí ó ti yẹ lọ. Tí wọ́n bá fi ìwọ̀n ọba wọn èyí tí wọ́n bá gé lára irun rẹ̀, a máa tó igba ṣekeli.

27. Absalomu bí ọmọkunrin mẹta ati ọmọbinrin kan. Tamari ni orúkọ ọmọbinrin yìí, ó sì jẹ́ arẹwà.

28. Ọdún meji ni Absalomu fi gbé Jerusalẹmu láì fi ojú kan ọba.

Ka pipe ipin Samuẹli Keji 14