17. Mo sì ti mọ̀ lọ́kàn ara mi pé, ọ̀rọ̀ tí kabiyesi bá sọ fún mi yóo fi mí lọ́kàn balẹ̀ nítorí pé, ọba dàbí angẹli Ọlọrun tí ó mọ ìyàtọ̀ láàrin ire ati ibi. OLUWA Ọlọrun rẹ̀ wà pẹlu rẹ̀.”
18. Ọba dá obinrin náà lóhùn pé, “Ọ̀rọ̀ kan ni mo fẹ́ bèèrè lọ́wọ́ rẹ, mo sì fẹ́ kí o sọ òtítọ́ rẹ̀ fún mi.”Obinrin náà dáhùn pé, “Kabiyesi, bèèrè ohunkohun tí o bá fẹ́.”
19. Ọba bá bí i pé, “Ṣé Joabu ni ó rán ọ ní gbogbo iṣẹ́ tí o wá jẹ́ yìí, àbí òun kọ?”Obinrin náà dáhùn pé, “Kabiyesi, bí o ti bèèrè ìbéèrè yìí kò jẹ́ kí n mọ̀ bí mo ti lè yí ẹnu pada rárá. Òtítọ́ ni, Joabu ni ó kọ́ mi ní gbogbo ohun tí mo sọ, ati gbogbo bí mo ti ṣe.