Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọmba 26:54-65 BIBELI MIMỌ (BM)

54. Fún àwọn tí ó pọ̀ ní ilẹ̀ pupọ ati àwọn tí ó kéré ní ilẹ̀ kéékèèké. Bí iye eniyan tí ó wà ninu ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan bá ti pọ̀ sí ni kí ẹ fi pín ilẹ̀ náà fún wọn.

55. Gègé ni kí ẹ ṣẹ́, kí ẹ fi pín ilẹ̀ náà fún olukuluku ẹ̀yà gẹ́gẹ́ bí iye wọn.

56. Gègé ni kí ẹ ṣẹ́ kí ẹ pín ilẹ̀ náà láàrin àwọn ẹ̀yà tí ó pọ̀ ati àwọn ẹ̀yà kéékèèké.”

57. Àwọn ọmọ Lefi ní ìdílé-ìdílé nìwọ̀nyí: ìdílé Geriṣoni, ìdílé Kohati ati ìdílé Merari,

58. Àwọn ìdílé tí ó wà ninu ẹ̀yà Lefi nìwọ̀nyí: ìdílé Libini, ìdílé Heburoni, ìdílé Mahili, ìdílé Muṣi ati ìdílé Kora. Kohati ni baba Amramu.

59. Orúkọ aya Amramu ni Jokebedi, ọmọbinrin Lefi tí ìyá rẹ̀ bí fún Lefi ní Ijipti. Ó bí Aaroni ati Mose ati Miriamu, arabinrin wọn fún Amramu.

60. Àwọn ọmọ Aaroni ni Nadabu, Abihu, Eleasari ati Itamari.

61. Nadabu ati Abihu kú nígbà tí wọ́n rúbọ sí OLUWA ninu Àgọ́ Àjọ pẹlu iná tí kò mọ́.

62. Gbogbo àwọn ọmọkunrin tí a kà ninu ẹ̀yà Lefi láti ẹni oṣù kan sókè jẹ́ ẹgbaa mọkanla ó lé ẹgbẹrun (23,000). Wọn kò kà wọ́n mọ́ àwọn ọmọ Israẹli nítorí pé wọn kò ní ilẹ̀ ìní ní Israẹli.

63. Gbogbo àwọn tí Mose ati Eleasari kà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Moabu lẹ́bàá Jọdani létí Jẹriko nìwọ̀nyí.

64. Ṣugbọn kò sí ẹnìkan tí ó tíì dáyé ninu wọn nígbà tí Mose ati Aaroni alufaa, ka àwọn ọmọ Israẹli ní aṣálẹ̀ Sinai.

65. Nítorí pé OLUWA ti sọ pé gbogbo àwọn ti ìgbà náà ni yóo kú ninu aṣálẹ̀. Kalebu ọmọ Jefune ati Joṣua ọmọ Nuni nìkan ni ó kù lára wọn.

Ka pipe ipin Nọmba 26