Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọmba 26:49-59 BIBELI MIMỌ (BM)

49. ìdílé Jeseri ati ìdílé Ṣilemu.

50. Gbogbo àwọn tí a kà ninu ẹ̀yà Nafutali jẹ́ ẹgbaa mejilelogun ó lé egbeje (45,400).

51. Gbogbo wọn ní àpapọ̀ jẹ́ ọgbọ̀n ọ̀kẹ́ ó lé ẹgbẹsan ó dín aadọrin (601,730).

52. OLUWA sọ fún Mose pé,

53. “Àwọn wọnyi ni kí o pín ilẹ̀ náà fún gẹ́gẹ́ bí iye wọn.

54. Fún àwọn tí ó pọ̀ ní ilẹ̀ pupọ ati àwọn tí ó kéré ní ilẹ̀ kéékèèké. Bí iye eniyan tí ó wà ninu ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan bá ti pọ̀ sí ni kí ẹ fi pín ilẹ̀ náà fún wọn.

55. Gègé ni kí ẹ ṣẹ́, kí ẹ fi pín ilẹ̀ náà fún olukuluku ẹ̀yà gẹ́gẹ́ bí iye wọn.

56. Gègé ni kí ẹ ṣẹ́ kí ẹ pín ilẹ̀ náà láàrin àwọn ẹ̀yà tí ó pọ̀ ati àwọn ẹ̀yà kéékèèké.”

57. Àwọn ọmọ Lefi ní ìdílé-ìdílé nìwọ̀nyí: ìdílé Geriṣoni, ìdílé Kohati ati ìdílé Merari,

58. Àwọn ìdílé tí ó wà ninu ẹ̀yà Lefi nìwọ̀nyí: ìdílé Libini, ìdílé Heburoni, ìdílé Mahili, ìdílé Muṣi ati ìdílé Kora. Kohati ni baba Amramu.

59. Orúkọ aya Amramu ni Jokebedi, ọmọbinrin Lefi tí ìyá rẹ̀ bí fún Lefi ní Ijipti. Ó bí Aaroni ati Mose ati Miriamu, arabinrin wọn fún Amramu.

Ka pipe ipin Nọmba 26