Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọmba 22:1-15 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Àwọn ọmọ Israẹli ṣí kúrò, wọ́n lọ pa àgọ́ wọn sí pẹ̀tẹ́lẹ̀ Moabu ní òdìkejì Jọdani tí ó kọjú sí Jẹriko.

2. Nígbà tí Balaki ọmọ Sipori, ọba Moabu rí gbogbo ohun tí àwọn ọmọ Israẹli ṣe sí àwọn ará Amori,

3. ẹ̀rù wọn ba òun ati àwọn eniyan rẹ̀ lọpọlọpọ, nítorí pé wọ́n pọ̀. Jìnnìjìnnì bo gbogbo àwọn ará Moabu nítorí àwọn ọmọ Israẹli.

4. Àwọn ará Moabu ranṣẹ sí àwọn olórí Midiani pé, “Àwọn eniyan wọnyi yóo run gbogbo ohun tí ó wà ní àyíká wa bí ìgbà tí mààlúù bá jẹ koríko ninu pápá.”

5. Nítorí náà, Balaki ọmọ Sipori, ọba Moabu ranṣẹ lọ pe Balaamu ọmọ Beori ní Petori lẹ́bàá Odò Yufurate ní ilẹ̀ Amawi pé, “Àwọn eniyan kan jáde ti ilẹ̀ Ijipti wá, wọ́n pàgọ́ sórí ilẹ̀ mi, wọ́n sì bo gbogbo ilẹ̀ náà.

6. Agbára wọn ju tèmi lọ, nítorí náà, wá bá mi ṣépè lé wọn, bóyá bí mo bá bá wọn jagun, n óo lè ṣẹgun wọn, kí n sì lé wọn kúrò lórí ilẹ̀ mi. Mo mọ̀ dájú pé ibukun ni fún ẹni tí o bá súre fún; ẹni tí o bá ṣépè fún, olúwarẹ̀ gbé!”

7. Àwọn àgbààgbà Moabu ati Midiani mú owó iṣẹ́ aláfọ̀ṣẹ lọ́wọ́, wọ́n tọ Balaamu wá, wọ́n sì jíṣẹ́ Balaki fún un.

8. Balaamu sọ fún wọn pé, “Ẹ sùn níbí ní alẹ́ yìí, bí ó bá di ọ̀la, n óo sọ ohun tí OLUWA bá sọ fún mi fun yín.” Àwọn àgbààgbà náà sì dúró lọ́dọ̀ Balaamu.

9. Ọlọrun tọ Balaamu wá, ó bi í pé, “Àwọn ọkunrin wo ni wọ́n wà lọ́dọ̀ rẹ yìí?”

10. Balaamu dáhùn pé, “Balaki ọba àwọn ará Moabu ni ó rán wọn sí mi pé,

11. àwọn eniyan kan, tí wọ́n wá láti Ijipti, tẹ̀dó sórí gbogbo ilẹ̀ òun. Ó fẹ́ kí n wá bá òun ṣépè lé wọn, kí ó lè bá wọn jà, kí ó sì lè lé wọn kúrò lórí ilẹ̀ rẹ̀.”

12. Ọlọrun sọ fún Balaamu pé, “Má bá wọn lọ, má sì ṣépè lé àwọn eniyan náà nítorí ẹni ibukun ni wọ́n.”

13. Nígbà tí Balaamu jí ní òwúrọ̀, ó sọ fún àwọn oníṣẹ́ Balaki pé, “Ẹ máa lọ sí ilẹ̀ yín nítorí OLUWA ti sọ pé n kò gbọdọ̀ ba yín lọ.”

14. Nígbà náà ni wọ́n pada lọ sọ́dọ̀ Balaki, wọn sì sọ fún un wí pé Balaamu kọ̀, kò bá àwọn wá.

15. Balaki tún rán àwọn àgbààgbà mìíràn tí wọ́n pọ̀, tí wọ́n sì ṣe pataki ju àwọn ti iṣaaju lọ sí ọ̀dọ̀ Balaamu.

Ka pipe ipin Nọmba 22