Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nehemaya 3:4-18 BIBELI MIMỌ (BM)

4. Lẹ́yìn wọn ni Meremoti, ọmọ Uraya, ọmọ Hakosi ṣe àtúnṣe abala ọ̀dọ̀ wọn.Lẹ́yìn wọn, Meṣulamu ọmọ Berekaya, ọmọ Meṣesabeli náà ṣe àtúnṣe abala ọ̀dọ̀ wọn.Lẹ́yìn wọn ni Sadoku, ọmọ Baana náà ṣe àtúnṣe abala tiwọn.

5. Lẹ́yìn wọn, àwọn ará Tekoa ṣe àtúnṣe ọ̀dọ̀ tiwọn, ṣugbọn àwọn ọlọ́lá ààrin wọn kò lọ́wọ́ sí iṣẹ́ àtúnṣe náà.

6. Joiada, ọmọ Pasea, ati Meṣulamu, ọmọ Besodeaya, ni wọ́n ṣe àtúnṣe Ẹnubodè Àtijọ́. Wọ́n ṣe ẹnu ọ̀nà, wọ́n ṣe àwọn ìlẹ̀kùn, wọ́n sì ṣe ọ̀pá ìdábùú sí wọn.

7. Lẹ́yìn wọn ni àwọn Melataya, ará Gibeoni, Jadoni, ará Meronoti, ati àwọn ará Gibeoni ati àwọn ará Misipa tí wọ́n wà ní abẹ́ ìjọba Ìkọjá Odò ṣe àtúnṣe abala ọ̀dọ̀ tiwọn.

8. Usieli ọmọ Hariaya alágbẹ̀dẹ wúrà ló ṣiṣẹ́ tẹ̀lé wọn.Lẹ́yìn wọn ni Hananaya, ọ̀kan ninu àwọn onítùràrí ṣe àtúnṣe ọ̀dọ̀ tirẹ̀, wọ́n sì ṣe é dé ibi Odi Gbígbòòrò.

9. Lẹ́yìn wọn ni Refaaya ọmọ Huri, aláṣẹ ìdajì agbègbè Jerusalẹmu ṣe àtúnṣe abala tí ó kàn.

10. Jedaaya ọmọ Harumafi ló ṣe àtúnṣe abala tí ó tẹ̀lé tiwọn, ó tún apá ibi tí ó kọjú sí ilé rẹ̀ ṣe.Lẹ́yìn wọn, Hatuṣi ọmọ Haṣabineya ṣe àtúnṣe tiwọn.

11. Malikija, ọmọ Harimu, ati Haṣubu, ọmọ Pahati Moabu, ṣe àtúnṣe apá ibòmíràn ati Ilé Ìṣọ́ ìléru.

12. Lẹ́yìn rẹ̀ ni Ṣalumu ọmọ Haloheṣi, aláṣẹ apá keji agbègbè Jerusalẹmu ṣe àtúnṣe apá ọ̀dọ̀ tirẹ̀, àtòun ati àwọn ọmọbinrin rẹ̀.

13. Hanuni ati àwọn tí ń gbé Sanoa tún Ẹnubodè Àfonífojì ṣe, wọ́n tún un kọ́, wọ́n sì ṣe àwọn ìlẹ̀kùn rẹ̀. Wọ́n ṣe àwọn ọ̀pá ìdábùú rẹ̀, wọ́n sì tún odi rẹ̀ kọ́ ní ìwọ̀n ẹgbẹrun igbọnwọ (mita 450), sí Ẹnubodè Ààtàn.

14. Malikija ọmọ Rekabu, aláṣẹ agbègbè Beti Hakikeremu, ṣe àtúnṣe Ẹnubodè Ààtàn, ó tún un kọ́, ó so àwọn ìlẹ̀kùn rẹ̀ ó sì ṣe àwọn ìdábùú rẹ̀.

15. Ṣalumu ọmọ Kolihose, aláṣẹ agbègbè Misipa tún Ẹnubodè Orísun ṣe, ó tún un kọ́, ó bò ó, ó sì ṣe àwọn ìlẹ̀kùn rẹ̀ ati ọ̀pá ìdábùú rẹ̀, ó sì tún mọ odi Adágún Ṣela ti ọgbà ọba títí kan àtẹ̀gùn tí ó wá láti ìlú Dafidi.

16. Lẹ́yìn rẹ̀, Nehemaya ọmọ Asibuki, aláṣẹ ìdajì agbègbè Betisuri ṣe àtúnṣe dé itẹ́ Dafidi, títí dé ibi adágún àtọwọ́dá ati títí dé ilé àwọn akọni.

17. Lẹ́yìn rẹ̀ ni àwọn ọmọ Lefi wọnyi ṣe àtúnṣe ọ̀dọ̀ tiwọn ní ìsọ̀rí-ìsọ̀rí: Rehumu ọmọ Bani ṣe àtúnṣe apá ọ̀dọ̀ tirẹ̀, lẹ́yìn rẹ̀ ni Haṣabaya, aláṣẹ ìdajì agbègbè Keila ṣe àtúnṣe agbègbè tirẹ̀.

18. Àwọn arakunrin rẹ̀ ṣe àtúnṣe agbègbè tiwọn náà: Bafai ọmọ Henadadi, aláṣẹ ìdajì agbègbè Keila ṣe ti agbègbè rẹ̀.

Ka pipe ipin Nehemaya 3