Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nehemaya 12:6-17 BIBELI MIMỌ (BM)

6. Ṣemaaya, Joiaribu ati Jedaaya,

7. Salu ati Amoku, Hilikaya, ati Jedaaya. Àwọn ni wọ́n jẹ́ olórí alufaa ati olórí àwọn arakunrin wọn ní ìgbà ayé Jeṣua.

8. Àwọn ọmọ Lefi ni: Jeṣua, Binui ati Kadimieli; Ṣerebaya, Juda, ati Matanaya, tí òun pẹlu àwọn arakunrin rẹ̀ wà nídìí ètò àwọn orin ọpẹ́.

9. Bakibukaya ati Uno arakunrin wọn a máa dúró kọjú sí wọn ní àkókò ìsìn.

10. Joṣua ni baba Joiakimu, Joiakimu ni baba Eliaṣibu, Eliaṣibu ni baba Joiada,

11. Joiada ni baba Jonatani, Jonatani sì ni baba Jadua.

12. Nígbà tí Joiakimu jẹ́ olórí alufaa, àwọn alufaa wọnyi ní olórí baálé ní ìdílé tí a dárúkọ wọnyi:Meraya ni baálé ní ìdílé Seraaya,Hananaya ni baálé ní ìdílé Jeremaya,

13. Meṣulamu ni baálé ní ìdílé Ẹsira,Jehohanani ni baálé ní ìdílé Amaraya,

14. Jonatani ni baálé ní ìdílé Maluki,Josẹfu ni baálé ní ìdílé Ṣebanaya,

15. Adina ni baálé ní ìdílé Harimu,Helikai ni baálé ní ìdílé Meraiotu,

16. Sakaraya ni baálé ní ìdílé Ido,Meṣulamu ni baálé ní ìdílé Ginetoni,

17. Sikiri ni baálé ní ìdílé Abija,Pilitai ni baálé ní ìdílé Miniamini ati Moadaya,

Ka pipe ipin Nehemaya 12