Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lefitiku 7:15-26 BIBELI MIMỌ (BM)

15. Wọ́n gbọdọ̀ jẹ́ ẹran ẹbọ alaafia tí ó fi ṣe ẹbọ ọpẹ́ tán ní ọjọ́ tí ó bá rú ẹbọ náà, kò gbọdọ̀ ṣẹ́kù di ọjọ́ keji.

16. “Ṣugbọn bí ẹbọ ọrẹ rẹ̀ bá jẹ́ ti ẹ̀jẹ́ tabi ọrẹ àtinúwá, wọ́n gbọdọ̀ jẹ ẹ́ ní ọjọ́ náà, ṣugbọn bí ó bá ṣẹ́kù, wọ́n lè jẹ ẹ́ ní ọjọ́ keji;

17. ṣugbọn bí ó bá ṣẹ́kù di ọjọ́ kẹta, sísun ni kí ó sun ún.

18. Bí wọ́n bá jẹ ninu ẹran ẹbọ alaafia tí ó bá ṣẹ́kù di ọjọ́ kẹta, ẹbọ náà kò ní jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà lọ́wọ́ ẹni tí ó bá rú u, a kò ní kọ ọ́ sílẹ̀ fún un, nítorí pé ohun ìríra ni, ẹni tí ó bá jẹ ẹ́ ni yóo ru ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.

19. Ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ jẹ ẹran tí ó bá kan ohun àìmọ́ kan, sísun ni ẹ gbọdọ̀ sun irú ẹran bẹ́ẹ̀.“Gbogbo àwọn tí wọ́n bá jẹ́ mímọ́ lè jẹ àwọn ẹran yòókù,

20. ṣugbọn ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ lára ẹran tí a fi rú ẹbọ alaafia sí OLUWA, ní àkókò tí òun fúnra rẹ̀ jẹ́ aláìmọ́, a óo yọ ọ́ kúrò lára àwọn eniyan Ọlọrun.

21. Bí ẹnikẹ́ni bá fọwọ́ kan ohun àìmọ́ kan, ìbáà ṣe ohun àìmọ́ ti eniyan, tabi ti ẹranko tabi ohun ìríra kan, lẹ́yìn náà tí ó wá jẹ ninu ẹran tí a fi rú ẹbọ alaafia sí OLUWA, a óo yọ ẹni náà kúrò lára àwọn eniyan Ọlọrun.”

22. OLUWA ní kí Mose sọ fún àwọn eniyan Israẹli pé,

23. “Ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ọ̀rákọ́ràá, ìbáà jẹ́ ti mààlúù tabi ti aguntan tabi ti ewúrẹ́.

24. Ẹ lè lo ọ̀rá ẹran tí ó kú fúnra rẹ̀ ati ọ̀rá èyí tí ẹranko burúkú pa, fún ohun mìíràn, ṣugbọn ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ẹ́.

25. Nítorí pé a óo yọ ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ ọ̀rá ẹran tí a fi rú ẹbọ sísun sí OLUWA, kúrò lára àwọn eniyan Ọlọrun.

26. Siwaju sí i, ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ẹ̀jẹ̀ ní gbogbo ibùgbé yín, bí ó ti wù kí ó rí; ìbáà jẹ́ ti ẹyẹ tabi ti ẹranko.

Ka pipe ipin Lefitiku 7