Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lefitiku 4:22-34 BIBELI MIMỌ (BM)

22. “Bí ìjòyè kan bá dẹ́ṣẹ̀, tí ó ṣèèṣì ṣe ọ̀kankan ninu àwọn ohun tí OLUWA Ọlọrun rẹ̀ pa láṣẹ pé ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ ṣe, tí ó sì jẹ̀bi,

23. nígbà tí wọ́n bá fi ẹ̀ṣẹ̀ tí ó dá yìí hàn án, yóo mú òbúkọ kan tí kò ní àbààwọ́n wá, yóo fi rúbọ.

24. Yóo gbé ọwọ́ lé orí òbúkọ yìí, yóo sì pa á níbi tí wọ́n ti máa ń pa ẹran ẹbọ sísun níwájú OLUWA; ó jẹ́ ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀.

25. Alufaa yóo ti ìka bọ inú ẹ̀jẹ̀ ẹran tí wọ́n fi rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ yìí yóo fi sí ara àwọn ìwo pẹpẹ ẹbọ sísun; yóo sì da ẹ̀jẹ̀ yòókù sílẹ̀ nídìí pẹpẹ.

26. Yóo sun gbogbo ọ̀rá òbúkọ náà lórí pẹpẹ, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rá ẹran tí wọ́n bá fi rú ẹbọ alaafia. Bẹ́ẹ̀ ni alufaa yóo ṣe ṣe ètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, OLUWA yóo sì dáríjì í.

27. “Bí ẹnìkan lásán ninu àwọn eniyan náà bá ṣèèṣì dẹ́ṣẹ̀, tí ó ṣe ọ̀kan ninu àwọn ohun tí OLUWA ti pa láṣẹ pé ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ ṣe, tí ó sì jẹ̀bi,

28. lẹ́yìn tí wọ́n bá fi ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ tí ó dá hàn án, yóo mú abo ewúrẹ́ tí kò ní àbààwọ́n wá, yóo fi rúbọ fún ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ti dá.

29. Yóo gbé ọwọ́ lé orí ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ yìí, yóo sì pa á, níbi tí wọ́n ti ń rú ẹbọ sísun.

30. Alufaa yóo sì ti ìka bọ inú ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, yóo fi sí ara ìwo pẹpẹ ẹbọ sísun, yóo sì da ẹ̀jẹ̀ yòókù sí ìdí pẹpẹ.

31. Yóo yọ gbogbo ọ̀rá ewúrẹ́ náà, bí wọ́n ti ń yọ ọ̀rá ẹran tí wọ́n bá fi rú ẹbọ alaafia, alufaa yóo sì sun ún níná lórí pẹpẹ gẹ́gẹ́ bí ẹbọ olóòórùn dídùn sí OLUWA. Alufaa yóo ṣe ètùtù fún un, OLUWA yóo sì dáríjì í.

32. “Bí ó bá jẹ́ pé, aguntan ni ó mú wá fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, ó níláti jẹ́ abo aguntan tí kò ní àbààwọ́n.

33. Kí ó gbé ọwọ́ lórí ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ yìí, kí ó sì pa á fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ níbi tí wọ́n ti ń pa ẹran tí wọ́n bá fẹ́ fi rú ẹbọ sísun.

34. Lẹ́yìn náà alufaa yóo yán ẹ̀jẹ̀ ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ náà sí ara ìwo pẹpẹ ẹbọ sísun, yóo wá da ẹ̀jẹ̀ yòókù sídìí pẹpẹ.

Ka pipe ipin Lefitiku 4