Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lefitiku 25:8-23 BIBELI MIMỌ (BM)

8. “Ẹ ka ìsinmi ọdún keje keje yìí lọ́nà meje, kí ọdún keje náà fi jẹ́ ọdún mọkandinlaadọta.

9. Nígbà tí ó bá di ọjọ́ kẹwaa oṣù keje tíí ṣe ọjọ́ ètùtù, ẹ óo rán ọkunrin kan kí ó lọ fọn fèrè jákèjádò gbogbo ilẹ̀ yín.

10. Ẹ ya ọdún tí ó gbẹ̀yìn aadọta ọdún náà sí mímọ́, kí ẹ sì kéde ìdáǹdè jákèjádò gbogbo ilẹ̀ yín fún gbogbo àwọn tí wọn ń gbé inú rẹ̀, yóo jẹ́ ọdún jubili fun yín. Ní ọdún náà, olukuluku yín yóo pada sórí ilẹ̀ rẹ̀ ati sinu ìdílé rẹ̀.

11. Ọdún jubili ni ọdún tí ó gbẹ̀yìn aadọta ọdún yìí yóo jẹ́ fun yín. Ninu ọdún náà, ẹ kò gbọdọ̀ gbin ohunkohun, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò gbọdọ̀ kórè ohun tí ó bá dá hù fúnra rẹ̀; bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò gbọdọ̀ ká àjàrà tí ó bá so ninu ọgbà àjàrà tí ẹ kò tọ́jú.

12. Nítorí pé, ọdún jubili ni yóo máa jẹ́ fun yín, yóo jẹ́ ọdún mímọ́ fun yín, ninu oko ni ẹ óo ti máa jẹ ohun tí ó bá so.

13. “Ní ọdún jubili yìí, olukuluku yín yóo pada sórí ilẹ̀ rẹ̀.

14. Nítorí náà, nígbà tí ẹ bá ta ilẹ̀ fún aládùúgbò yín, tabi tí ẹ bá ń ra ilẹ̀ lọ́wọ́ rẹ̀, ẹ kò gbọdọ̀ ṣe àìdára sí ara yín.

15. Iye ọdún tí ó bá ti rékọjá lẹ́yìn ọdún jubili ni ẹ óo máa wò ra ilẹ̀ lọ́wọ́ aládùúgbò yín, iye ọdún tí ẹ bá fi lè gbin ohun ọ̀gbìn sórí ilẹ̀ kan kí ọdún jubili tó dé ni òun náà yóo máa wò láti tà á fun yín.

16. Tí ó bá jẹ́ pé ọdún pupọ ni ó kù, owó ilẹ̀ náà yóo pọ̀, ṣugbọn bí ó bá jẹ́ pé ọdún díẹ̀ ni, owó rẹ̀ yóo wálẹ̀; nítorí pé, iye ọdún tí ó bá lè fi gbin ohun ọ̀gbìn sórí ilẹ̀ náà ni yóo wò láti ta ilẹ̀ náà.

17. Ẹ kò gbọdọ̀ ṣe àìdára sí ara yín, ṣugbọn ẹ bẹ̀rù Ọlọrun yín; nítorí èmi ni OLUWA Ọlọrun yín.

18. “Nítorí náà, ẹ níláti tẹ̀lé ìlànà mi, kí ẹ sì pa òfin mi mọ́, kí ẹ lè máa gbé inú ilẹ̀ náà láìséwu.

19. Ilẹ̀ náà yóo so ọpọlọpọ èso, ẹ óo jẹ àjẹyó, ẹ óo sì máa gbé inú rẹ̀ láìséwu.

20. “Bí ẹ bá ń wí pé, ‘Kí ni a óo jẹ ní ọdún keje bí a kò bá gbọdọ̀ gbin ohun ọ̀gbìn, tí a kò sì gbọdọ̀ kórè?’

21. Èmi OLUWA yóo pàṣẹ pé kí ibukun mi wà lórí yín ní ọdún kẹfa tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi jẹ́ pé ilẹ̀ yóo so èso tí yóo to yín jẹ fún ọdún mẹta.

22. Nígbà tí ẹ bá gbin ohun ọ̀gbìn ní ọdún kẹjọ, ẹ óo tún máa rí àwọn èso tí ó ti wà ní ìpamọ́ jẹ títí tí yóo fi di ọdún kẹsan-an, tí ilẹ̀ yóo tún mú èso rẹ̀ jáde wá, àwọn èso ti àtẹ̀yìnwá ni ẹ óo máa jẹ.

23. “Ẹ kò gbọdọ̀ ta ilẹ̀ kan títí ayé, nítorí pé èmi OLUWA ni mo ni gbogbo ilẹ̀, ati pé àlejò ati àtìpó ni ẹ jẹ́ fún mi.

Ka pipe ipin Lefitiku 25