Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lefitiku 22:9-21 BIBELI MIMỌ (BM)

9. “Àwọn alufaa gbọdọ̀ pa àwọn òfin mi mọ́, kí wọ́n má baà dẹ́ṣẹ̀ nítorí rẹ̀, kí wọ́n sì kú nítorí àwọn òfin mi tí wọ́n bá rú. Èmi ni OLUWA tí mo sọ wọ́n di mímọ́.

10. “Àjèjì kankan kò gbọdọ̀ jẹ ninu àwọn ohun mímọ́, bẹ́ẹ̀ ni àlejò tabi alágbàṣe tí ń gbé ilé alufaa kò gbọdọ̀ jẹ ninu wọn.

11. Ṣugbọn bí alufaa bá fi owó ra ẹrú fún ara rẹ̀, ẹrú náà lè jẹ ninu àwọn ohun mímọ́ náà. Àwọn ọmọ tí ẹrú náà bá sì bí ninu ilé alufaa náà lè jẹ ninu oúnjẹ náà pẹlu.

12. Bí ọmọbinrin alufaa kan bá fẹ́ àjèjì, kò gbọdọ̀ jẹ ninu àwọn ohun mímọ́ tí wọ́n bá fi rúbọ.

13. Ṣugbọn bí ọmọbinrin alufaa kan bá jẹ́ opó, tabi tí ó ti kọ ọkọ rẹ̀ sílẹ̀ láì bímọ fún un, tí ó bá pada sí ilé baba rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí ó wà ní ọdọmọbinrin, ó lè jẹ ninu oúnjẹ baba rẹ̀; sibẹsibẹ àjèjì kankan kò gbọdọ̀ jẹ ninu rẹ̀.

14. “Bí ẹnìkan bá jẹ ohun mímọ́ kan ní ìjẹkújẹ yóo san án pada fún alufaa pẹlu ìdámárùn-ún rẹ̀.

15. Àwọn alufaa kò gbọdọ̀ sọ àwọn ohun mímọ́ àwọn eniyan Israẹli tí wọ́n fi ń rúbọ sí OLUWA di aláìmọ́.

16. Kí wọ́n má baà mú àwọn eniyan náà dẹ́ṣẹ̀, kí wọ́n sì kó ẹ̀bi rù wọ́n nípa jíjẹ àwọn ohun mímọ́ wọn; nítorí èmi ni OLUWA tí mo sọ wọ́n di mímọ́.”

17. OLUWA tún rán Mose pé

18. kí ó sọ fún Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin, ati gbogbo àwọn eniyan Israẹli pé: “Nígbà tí ẹnìkan ninu àwọn eniyan Israẹli tabi àlejò tí ó wà láàrin wọn bá mú ohun ìrúbọ rẹ̀ wá, kì báà ṣe pé láti fi san ẹ̀jẹ́ kan ni, tabi gẹ́gẹ́ bí ọrẹ àtinúwá, láti fi rú ẹbọ sísun sí OLUWA,

19. kí ohun ìrúbọ náà baà lè jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà, ó níláti jẹ́ akọ, tí kò ní àbùkù, ó lè jẹ́ akọ mààlúù, tabi àgbò, tabi òbúkọ.

20. Ẹ kò gbọdọ̀ fi ohunkohun tí ó bá ní àbààwọ́n rúbọ, nítorí pé, OLUWA kò ní tẹ́wọ́gbà á lọ́wọ́ yín.

21. Nígbà tí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ rú ẹbọ alaafia sí OLUWA láti san ẹ̀jẹ́, tabi fún ọrẹ àtinúwá; kì báà jẹ́ láti inú agbo mààlúù tabi láti inú agbo aguntan ni yóo ti mú ẹran ìrúbọ yìí, ó níláti jẹ́ pípé, kò gbọdọ̀ ní àbùkù kan lára, kí ẹbọ náà lè jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà.

Ka pipe ipin Lefitiku 22