Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lefitiku 17:1-12 BIBELI MIMỌ (BM)

1. OLUWA sọ fún Mose pé

2. kí ó sọ fún Aaroni, ati àwọn ọmọkunrin rẹ̀, ati gbogbo àwọn ọmọ Israẹli pé, “Ohun tí OLUWA paláṣẹ nìyí:

3. Bí ẹnìkan ninu àwọn ọmọ Israẹli bá pa akọ mààlúù, tabi ọ̀dọ́ aguntan, tabi ewúrẹ́ kan ní ibùdó, tabi lẹ́yìn ibùdó,

4. tí kò bá mú un wá sí ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ láti fi ṣe ẹ̀bùn fún OLUWA níwájú Àgọ́ mímọ́ rẹ̀, olúwarẹ̀ yóo jẹ̀bi ìtàjẹ̀sílẹ̀, ó ti ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀, a óo sì yọ ọ́ kúrò láàrin àwọn eniyan rẹ̀.

5. OLUWA pa àṣẹ yìí kí àwọn ọmọ Israẹli lè máa mú ẹran ìrúbọ tí wọ́n bá pa ninu pápá wá fún OLUWA, kí wọn mú un tọ alufaa wá lẹ́nu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ, kí wọn sì pa á láti fi rú ẹbọ alaafia sí OLUWA.

6. Alufaa yóo sì máa wọ́n ẹ̀jẹ̀ wọn sí ara pẹpẹ OLUWA lẹ́nu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ, yóo sì sun ọ̀rá wọn bí ẹbọ sísun olóòórùn dídùn sí OLUWA.

7. Kí àwọn ọmọ Israẹli má baà tún máa fi ẹran wọn rúbọ sí oriṣa bí wọ́n ti ń ṣe rí. Òfin yìí wà fún arọmọdọmọ wọn títí lae.

8. “Bákan náà, ẹnikẹ́ni ninu àwọn ọmọ Israẹli tabi àlejò tí ń ṣe àtìpó láàrin wọn, tí ó bá rú ẹbọ sísun tabi ẹbọ mìíràn,

9. tí kò bá mú ẹran tí yóo fi rú ẹbọ náà wá sí ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ láti fi rúbọ sí OLUWA, a óo yọ ẹni náà kúrò láàrin àwọn eniyan rẹ̀.

10. “Bí ẹnikẹ́ni ninu àwọn ọmọ Israẹli tabi àlejò tí ń ṣe àtìpó láàrin wọn bá jẹ ẹ̀jẹ̀, èmi OLUWA yóo bínú sí olúwarẹ̀, n óo sì yọ ọ́ kúrò láàrin àwọn eniyan rẹ̀.

11. Nítorí pé, ninu ẹ̀jẹ̀ ni ẹ̀mí ohun alààyè gbogbo wà; mo sì ti fun yín, pé kí ẹ máa ta á sórí pẹpẹ, kí ẹ máa fi ṣe ètùtù fún ẹ̀mí yín; nítorí pé ẹ̀jẹ̀ níí ṣe ètùtù, nítorí ẹ̀mí tí ó wà ninu rẹ̀.

12. Nítorí rẹ̀ ni mo fi sọ fún ẹ̀yin ọmọ Israẹli pé, ẹnikẹ́ni ninu yín kò gbọdọ̀ jẹ ẹ̀jẹ̀, bẹ́ẹ̀ sì ni àlejò tí ń ṣe àtìpó láàrin yín kò gbọdọ̀ jẹ ẹ̀jẹ̀.

Ka pipe ipin Lefitiku 17