Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lefitiku 14:1-7 BIBELI MIMỌ (BM)

1. OLUWA sọ fún Mose pé,

2. “Òfin tí ó jẹmọ́ ti ọjọ́ ìwẹ̀nùmọ́ adẹ́tẹ̀ nìyí: kí wọ́n mú adẹ́tẹ̀ náà wá sí ọ̀dọ̀ alufaa.

3. Kí alufaa jáde kúrò ninu àgọ́, kí ó sì yẹ̀ ẹ́ wò bí àrùn ẹ̀tẹ̀ náà bá ti san.

4. Alufaa yóo pàṣẹ pé kí wọ́n bá ẹni tí wọ́n fẹ́ ṣe ìwẹ̀nùmọ́ fún mú ẹyẹ mímọ́ meji wá ati igi kedari, pẹlu aṣọ pupa tẹ́ẹ́rẹ́ kan, ati ewé hisopu.

5. Alufaa yóo pàṣẹ pé kí wọ́n pa ọ̀kan ninu àwọn ẹyẹ náà sinu ìkòkò amọ̀, lórí odò tí ń ṣàn.

6. Yóo mú ẹyẹ tí ó wà láàyè ati igi kedari, ati aṣọ pupa tẹ́ẹ́rẹ́, ati ewé hisopu, yóo pa wọ́n pọ̀, yóo sì tì wọ́n bọ inú ẹ̀jẹ̀ ẹyẹ tí wọ́n pa lórí odò tí ń ṣàn.

7. Yóo wọ́n ọn sí ara ẹni tí wọ́n fẹ́ wẹ̀ mọ́ kúrò ninu àrùn ẹ̀tẹ̀ náà nígbà meje. Lẹ́yìn náà alufaa yóo pè é ní mímọ́, yóo sì jẹ́ kí ẹyẹ keji tí ó wà láàyè, fò wọ igbó lọ.

Ka pipe ipin Lefitiku 14