Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lefitiku 13:39-55 BIBELI MIMỌ (BM)

39. kí alufaa yẹ̀ ẹ́ wò, bí ọ̀gangan ibẹ̀ bá funfun díẹ̀ tí ó dúdú díẹ̀, ara olúwarẹ̀ kàn fín lásán ni, ó mọ́.

40. “Bí irun orí ọkunrin bá re, orí rẹ̀ pá ni, ṣugbọn ó mọ́.

41. Bí irun orí ẹnìkan bá re, ní gbogbo iwájú títí dé ẹ̀bá etí rẹ̀, orí rẹ̀ pá ni; ó mọ́.

42. Ṣugbọn bí ibi tí ó pá ní orí rẹ̀ tabi iwájú rẹ̀ yìí bá lé, tí ó sì pọ́n, ẹ̀tẹ̀ ni ó fẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí jẹ jáde níbi tí orí tabi iwájú rẹ̀ ti pá.

43. Kí alufaa yẹ̀ ẹ́ wò, tí ibi tí àrùn yìí ti wú ní orí tabi iwájú rẹ̀ bá pọ́n, tí ó sì dàbí ẹ̀tẹ̀ lára rẹ̀,

44. adẹ́tẹ̀ ni ọkunrin náà, kò mọ́; alufaa sì gbọdọ̀ pè é ní aláìmọ́. Orí rẹ̀ ni àrùn yìí wà.

45. “Ẹni tí ó ní àrùn ẹ̀tẹ̀ yìí gbọdọ̀ wọ aṣọ tí ó ya, kí ó fi apá kan irun orí rẹ̀ sílẹ̀ játijàti, kí ó bo ètè rẹ̀ òkè, kí ó sì máa ké pé, ‘Aláìmọ́! Aláìmọ́!’

46. Yóo jẹ́ aláìmọ́, níwọ̀n ìgbà tí àrùn yìí bá wà lára rẹ̀. Ó jẹ́ aláìmọ́; òun nìkan ni yóo sì máa dá gbé lẹ́yìn ibùdó.

47. “Nígbà tí àrùn ẹ̀tẹ̀ bá wà lára aṣọ kan, kì báà jẹ́ pé òwú tabi irun tí wọ́n fi hun aṣọ náà,

48. tabi lára aṣọkáṣọ, kì báà jẹ́ olówùú tabi onírun, tabi lára awọ, tabi lára ohunkohun tí a fi awọ ṣe.

49. Bí ibi tí àrùn yìí wà bá bẹ̀rẹ̀ sí í pọ́n tabi, kí ó ní àwọ̀ bíi ti ewéko, kì báà jẹ́ aṣọ olówùú, tabi ti onírun, tabi kí ó jẹ́ awọ tabi ohunkohun tí a fi awọ ṣe, àrùn ẹ̀tẹ̀ ni; dandan ni kí wọ́n fihan alufaa.

50. Kí alufaa yẹ àrùn náà wò, kí ó sì ti aṣọ tí àrùn náà ràn mọ́ mọ́lé fún ọjọ́ meje.

51. Kí ó yẹ àrùn ara aṣọ náà wò ní ọjọ́ keje, bí ó bá ti tàn káàkiri lára aṣọ tabi awọ náà, ohun yòówù tí wọ́n lè máa fi aṣọ náà ṣe, irú ẹ̀tẹ̀ tí ó máa ń ràn káàkiri ni; kò mọ́.

52. Kí alufaa jó aṣọ náà, ibi yòówù tí àrùn náà lè wà lára rẹ̀, kì báà jẹ́ aṣọ onírun tabi olówùú, tabi ohunkohun tí wọ́n fi awọ ṣe; nítorí pé irú àrùn tí ó máa ń ràn káàkiri ara ni; jíjó ni kí wọ́n jó o níná.

53. “Bí alufaa bá yẹ̀ ẹ́ wò, tí àrùn náà kò bá ràn káàkiri lára aṣọ náà tabi ohun èlò awọ náà,

54. alufaa yóo pàṣẹ pé kí wọ́n fọ ohun èlò tí àrùn wà lára rẹ̀ yìí, yóo sì tún tì í mọ́lé fún ọjọ́ meje sí i.

55. Alufaa yóo tún yẹ ohun èlò tí àrùn náà ràn mọ́ wò lẹ́yìn tí wọ́n bá ti fọ̀ ọ́. Bí ọ̀gangan ibi tí àrùn yìí ràn mọ́ kò bá mọ́, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò tàn káàkiri sí i; sibẹ kò mọ́; jíjó ni ó níláti jó o níná, kì báà jẹ́ iwájú, tabi ẹ̀yìn aṣọ tabi awọ náà ni àrùn ràn mọ́.

Ka pipe ipin Lefitiku 13