Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lefitiku 13:22-31 BIBELI MIMỌ (BM)

22. Bí àrùn yìí bá bẹ̀rẹ̀ sí tàn káàkiri lára olúwarẹ̀, kí alufaa pè é ní aláìmọ́; àrùn ẹ̀tẹ̀ ni.

23. Ṣugbọn bí àmì yìí kò bá paradà níbi tí ó wà, tí kò sì tàn káàkiri, àpá oówo lásán ni, kí alufaa pe ẹni náà ní mímọ́.

24. “Tabi bí iná bá jó eniyan lára, tí ó sì di egbò, tí ọ̀gangan ibẹ̀ bá pọ́n tabi tí ó funfun,

25. kí alufaa yẹ̀ ẹ́ wò. Bí irun ọ̀gangan ibẹ̀ bá funfun, tí ó sì jìn ju awọ ara rẹ̀ lọ, àrùn ẹ̀tẹ̀ ni; ẹ̀tẹ̀ ni ó jẹ jáde níbi tí iná ti jó olúwarẹ̀. Kí alufaa pè é ní aláìmọ́; àrùn ẹ̀tẹ̀ ni.

26. Ṣugbọn bí alufaa bá yẹ̀ ẹ́ wò, tí irun ọ̀gangan ibẹ̀ kò funfun, tí kò sì jìn ju awọ ara rẹ̀ lọ, ṣugbọn tí ó wòdú, kí alufaa ti ẹni náà mọ́lé fún ọjọ́ meje.

27. Ní ọjọ́ keje kí alufaa yẹ̀ ẹ́ wò, tí àrùn náà bá ti bẹ̀rẹ̀ sí tàn káàkiri ara rẹ̀, kí alufaa pe ẹni náà ní aláìmọ́; àrùn ẹ̀tẹ̀ ni.

28. Bí ibi tí ó wú yìí bá wà bí ó ṣe wà, tí kò sì tàn káàkiri, ṣugbọn tí ó wòdú; àpá iná lásán ni, kí alufaa pè é ní mímọ́.

29. “Bí ọkunrin tabi obinrin bá ní àrùn kan ní orí tabi ní irùngbọ̀n,

30. kí alufaa yẹ̀ ẹ́ wò, bí ó bá jìn wọnú ju awọ ara lọ, tí irun ọ̀gangan ibẹ̀ bá pọ́n, tí ó sì fẹ́lẹ́, kí alufaa pè é ní aláìmọ́; àrùn ẹ̀yi ni, tíí ṣe àrùn ẹ̀tẹ̀ irun orí tabi ti irùngbọ̀n.

31. Bí alufaa bá yẹ àrùn ẹ̀yi yìí wò, tí kò bá jìn ju awọ ara lọ, tí irun dúdú kò sì hù jáde ninu rẹ̀, kí alufaa ti ẹni náà mọ́lé fún ọjọ́ meje.

Ka pipe ipin Lefitiku 13