Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lefitiku 11:35-47 BIBELI MIMỌ (BM)

35. Ohunkohun tí apákan ninu òkú wọn bá jábọ́ lé lórí di aláìmọ́, kì báà jẹ́ ààrò tabi àdògán, o gbọdọ̀ fọ́ ọ túútúú; wọ́n jẹ́ aláìmọ́, wọ́n sì gbọdọ̀ jẹ́ aláìmọ́ fun yín.

36. Tí ó bá jẹ́ odò, tabi kànga tí ó ní omi ni, wọn kì í ṣe aláìmọ́, ṣugbọn gbogbo nǹkan yòókù tí ó fara kan òkú wọn di aláìmọ́.

37. Bí apákan ninu òkú wọn bá jábọ́ lé orí èso tí eniyan fẹ́ gbìn, èso náà kò di aláìmọ́.

38. Ṣugbọn bí eniyan bá da omi lé èso náà lórí, tí apákan ninu òkú wọn sì já lé èso náà, ó di aláìmọ́ fun yín.

39. “Bí ọ̀kankan ninu àwọn ẹran tí ẹ lè jẹ bá kú, ẹnikẹ́ni tí ó bá fara kan òkú rẹ̀ di aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́.

40. Ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ òkú ẹran náà níláti fọ aṣọ rẹ̀, yóo sì jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́. Ẹni tí ó bá ru òkú ẹran náà gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀, yóo sì jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ náà.

41. “Ohunkohun tí ń fi àyà fà lórí ilẹ̀ ayé jẹ́ ìríra, ẹnikẹ́ni kò sì gbọdọ̀ jẹ ẹ́.

42. Ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ohunkohun tí ó bá ń fi àyà wọ́, tabi ohunkohun tí ó bá ń fi ẹsẹ̀ mẹrin rìn tabi ohunkohun tí ó ní ọpọlọpọ ẹsẹ̀, tabi ohunkohun tí ó ń fà lórí ilẹ̀, nítorí ohun ìríra ni wọ́n.

43. Ẹ kò gbọdọ̀ fi ohunkohun tí ń fi àyà fà lórí ilẹ̀ sọ ara yín di ìríra; ẹ kò gbọdọ̀ kó ẹ̀gbin bá ara yín, kí ẹ má baà di aláìmọ́.

44. Nítorí pé, èmi ni OLUWA Ọlọrun yín, ẹ ya ara yín sí mímọ́, kí ẹ sì jẹ́ mímọ́, nítorí mímọ́ ni èmi Ọlọrun. Ẹ kò gbọdọ̀ fi ohunkohun tí ń fi àyà fà lórí ilẹ̀ sọ ara yín di aláìmọ́.

45. Nítorí èmi ni OLUWA tí ó ko yín jáde láti ilẹ̀ Ijipti wá, láti jẹ́ Ọlọrun yín; nítorí náà, ẹ níláti jẹ́ mímọ́, nítorí pé, mímọ́ ni èmi Ọlọrun.”

46. Èyí ni òfin tí ó jẹ mọ́ àwọn ẹranko ati ẹyẹ ati àwọn ẹ̀dá alààyè tí wọn wà ninu omi ati àwọn ẹ̀dá alààyè tí wọ́n ń fi àyà fà lórí ilẹ̀,

47. láti fi ìyàtọ̀ sí ààrin ohun tí ó mọ́, ati ohun tí kò mọ́, ati sí ààrin ẹ̀dá alààyè tí eniyan lè jẹ, ati ẹ̀dá alààyè tí eniyan kò gbọdọ̀ jẹ.

Ka pipe ipin Lefitiku 11