Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kronika Kinni 26:13-25 BIBELI MIMỌ (BM)

13. Gègé ni wọ́n ṣẹ́ fún ìdílé kọ̀ọ̀kan, láti mọ ẹnu ọ̀nà tí wọn yóo máa ṣọ́, wọn ìbáà jẹ́ eniyan yẹpẹrẹ, wọn ìbáà sì jẹ́ eniyan pataki.

14. Ṣelemaya ni gègé mú fún ẹnu ọ̀nà tí ó wà ní apá ìlà oòrùn. Sakaraya, ọmọ rẹ̀, olùdámọ̀ràn tí ó mòye, ni gègé mú fún ẹnu ọ̀nà ti ìhà àríwá.

15. Obedi Edomu ni gègé mú fún ẹnu ọ̀nà ti ìhà gúsù; àwọn ọmọ rẹ̀ ni a sì yàn láti máa ṣọ́ ilé ìṣúra.

16. Gègé mú Ṣupimu ati Hosa fún ẹnu ọ̀nà apá ìwọ̀ oòrùn ati ẹnu ọ̀nà Ṣaleketi, ní ojú ọ̀nà tí ó lọ sí òkè. Olukuluku àwọn aṣọ́nà ni ó ní àkókò iṣẹ́ tirẹ̀.

17. Àwọn eniyan mẹfa ni wọ́n ń ṣọ́ ẹnu ọ̀nà apá ìwọ̀ oòrùn ní ojoojumọ, àwọn mẹrin ń ṣọ́ ìhà àríwá, àwọn mẹrin ń ṣọ́ ìhà gúsù, àwọn meji meji sì ń ṣọ́ ilé ìṣúra.

18. Fún àgọ́ tí ó wà ní ìwọ̀ oòrùn, àwọn mẹrin ń ṣọ́ ojú ọ̀nà, àwọn meji sì ń ṣọ́ àgọ́ alára.

19. Bẹ́ẹ̀ ni a ṣe pín iṣẹ́ fún àwọn aṣọ́nà láti inú ìran Kora ati ti Merari.

20. Ahija, láti inú ẹ̀yà Lefi, ni ó ń bojútó àwọn ibi ìṣúra tí ó wà ninu ilé OLUWA ati ibi tí wọn ń kó àwọn ẹ̀bùn tí a yà sọ́tọ̀ fún Ọlọrun sí.

21. Ladani, ọ̀kan ninu ìran Geriṣoni, ní àwọn ọmọkunrin tí wọ́n jẹ́ olórí ìdílé wọn, ọ̀kan ninu wọn ń jẹ́ Jehieli.

22. Àwọn ọmọ Jehieli meji: Setamu ati Joẹli ni wọ́n ń bojútó àwọn ibi ìṣúra tí ó wà ninu ilé OLUWA.

23. A pín iṣẹ́ fún àwọn ọmọ Amramu, ati àwọn ọmọ Iṣari, ati àwọn ọmọ Heburoni ati àwọn ọmọ Usieli.

24. Ṣebueli, ọmọ Geriṣomu, láti inú ìran Mose, ni olórí àwọn tí ń bojútó ibi ìṣúra.

25. Ninu àwọn arakunrin Ṣebueli, láti ìdílé Elieseri, a yan Rehabaya ọmọ Elieseri, Jeṣaaya ọmọ Rehabaya, Joramu ọmọ Jeṣaaya, Sikiri ọmọ Joramu ati Ṣelomiti ọmọ Sikiri.

Ka pipe ipin Kronika Kinni 26