Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kronika Keji 35:13-23 BIBELI MIMỌ (BM)

13. Wọ́n sun ọ̀dọ́ aguntan Ìrékọjá gẹ́gẹ́ bí ìlànà. Wọ́n bọ ẹran ẹbọ mímọ́ ninu ìkòkò, ìsaasùn ati apẹ, wọ́n sì pín in fún àwọn eniyan lẹsẹkẹsẹ.

14. Lẹ́yìn náà, wọ́n tọ́jú tiwọn ati ti àwọn alufaa, àwọn ọmọ Aaroni. Nítorí iṣẹ́ ṣíṣe kò jẹ́ kí àwọn alufaa rí ààyè, láti àárọ̀ títí di alẹ́. Wọ́n ń rú ẹbọ sísun, wọ́n sì ń sun ọ̀rá ẹran níná. Nítorí náà ni àwọn ọmọ Lefi fi tọ́jú tiwọn, tí wọ́n sì tọ́jú ti àwọn alufaa, àwọn ọmọ Aaroni.

15. Àwọn akọrin tí wọ́n jẹ́ ọmọ Asafu dúró ní ipò wọn gẹ́gẹ́ bí àṣẹ Dafidi. Bẹ́ẹ̀ náà ni Asafu, Hemani, ati Jedutuni, aríran ọba. Àwọn aṣọ́nà tẹmpili kò kúrò ní ààyè wọn, nítorí pé àwọn ọmọ Lefi ti tọ́jú ẹbọ ìrékọjá tiwọn fún wọn.

16. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe ìsìn Àjọ Ìrékọjá ati ti ẹbọ sísun lórí pẹpẹ OLUWA ní ọjọ́ náà gẹ́gẹ́ bí àṣẹ Josaya ọba.

17. Àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n wá ṣe àsè Àjọ Ìrékọjá, wọ́n sì ṣe Àjọ Àìwúkàrà fún ọjọ́ meje.

18. Kò tíì sí irú àsè Àjọ Ìrékọjá bẹ́ẹ̀ ní gbogbo ilẹ̀ Israẹli láti ìgbà ayé wolii Samuẹli. Kò sì tíì sí ọba kankan ní Israẹli tí ó tíì ṣe àsè Àjọ Ìrékọjá bí Josaya ti ṣe pẹlu àwọn alufaa, àwọn ọmọ Lefi, àwọn eniyan Juda, àwọn tí wọ́n wá láti Israẹli ati àwọn ará Jerusalẹmu.

19. Ní ọdún kejidinlogun ìjọba Josaya ni wọ́n ṣe Àjọ Ìrékọjá yìí.

20. Nígbà tí ó yá lẹ́yìn tí Josaya ti ṣe ètò inú tẹmpili tán, Neko, ọba Ijipti wá jagun ní Kakemiṣi, ní odò Yufurate. Josaya sì digun lọ bá a jà.

21. Neko rán ikọ̀ sí Josaya pé, “Kí ló lè fa ìjà láàrin wa, ìwọ ọba Juda? Ìwọ kọ́ ni mo wá bá jà lákòókò yìí, orílẹ̀-èdè tí èmi pẹlu rẹ̀ ní ìjà ni mo wá bá jà. Ọlọrun ni ó sì sọ fún mi pé kí n má jáfara, má ṣe dojú ìjà kọ Ọlọrun, nítorí pé ó wà pẹlu mi; kí ó má ba à pa ọ́ run.”

22. Ṣugbọn Josaya ṣe oríkunkun, ó paradà kí wọ́n má baà dá a mọ̀, ó lọ bá a jà. Kò fetí sí ọ̀rọ̀ Neko, tí Ọlọrun sọ, ó lọ bá Neko jà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Megido.

23. Àwọn tafàtafà ta Josaya ọba ní ọfà, ó bá pe àwọn iranṣẹ rẹ̀, ó sì sọ fún wọn pé, “Ẹ gbé mi kúrò lójú ogun, nítorí mo ti fara gbọgbẹ́, ọgbẹ́ náà sì pọ̀.”

Ka pipe ipin Kronika Keji 35