Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kronika Keji 34:23-33 BIBELI MIMỌ (BM)

23. Ó bá dá wọn lóhùn pé, “OLUWA Ọlọrun Israẹli ní kí n sọ fun yín, kí ẹ sọ fún ẹni tí ó ran yín sí mi pé

24. òun OLUWA ní òun óo mú ibi wá sórí ibí yìí ati àwọn eniyan ibẹ̀ gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ sinu ìwé tí a kà sí ọba Juda létí.

25. Nítorí pé wọ́n ti kọ òun OLUWA sílẹ̀, wọ́n sì ń sun turari sí àwọn oriṣa, kí wọ́n lè fi ìṣe wọn mú òun bínú; nítorí náà òun óo bínú sí ibí yìí, kò sí ẹni tí yóo lè dá ibinu òun dúró.

26. Ó ní kí ẹ sọ ohun tí ẹ ti gbọ́ fún ọba Juda tí ó ranṣẹ láti wá wádìí lọ́wọ́ OLUWA Ọlọrun pé, èmi OLUWA Ọlọrun Israẹli ní,

27. nítorí pé nígbà tí ó gbọ́ nípa ìyà tí n óo fi jẹ Jerusalẹmu ati àwọn tí ń gbé ibẹ̀, ó ronupiwada, ó rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ níwájú mi, ó fa aṣọ rẹ̀ ya, ó sì sọkún níwájú mi, mo sì ti gbọ́ adura rẹ̀.

28. Nítorí náà, ìdájọ́ tí mo ti pinnu sórí Jerusalẹmu kò ní ṣẹlẹ̀ ní ìgbà ayé rẹ̀, ikú wọ́ọ́rọ́ ni yóo sì kú.”Àwọn eniyan náà bá pada lọ jíṣẹ́ fún ọba.

29. Lẹ́yìn náà, Josaya ọba ranṣẹ pe gbogbo àwọn àgbààgbà Juda ati ti Jerusalẹmu.

30. Ó bá lọ sí ilé OLUWA pẹlu gbogbo ará Juda, ati àwọn tí wọn ń gbé Jerusalẹmu; ati àwọn alufaa, ati àwọn ọmọ Lefi ati àwọn eniyan yòókù; ati olówó ati talaka. Ọba ka ìwé majẹmu tí wọ́n rí ninu ilé OLUWA sí etígbọ̀ọ́ wọn.

31. Ó dúró ní ààyè rẹ̀, ó sì bá OLUWA dá majẹmu pé òun óo máa fi tọkàntọkàn rìn ní ọ̀nà OLUWA, òun óo máa pa òfin rẹ̀ mọ́, òun óo máa mú àṣẹ rẹ̀ ṣẹ, òun ó sì máa tẹ̀lé ìlànà rẹ̀. Ó ní òun ó máa fi tọkàntọkàn pa majẹmu tí a kọ sinu ìwé náà mọ́.

32. Lẹ́yìn náà, ó ní kí àwọn ẹ̀yà Bẹnjamini ati àwọn ará Jerusalẹmu bá OLUWA dá majẹmu kí wọ́n sì pa á mọ́. Àwọn ará Jerusalẹmu sì pa majẹmu OLUWA Ọlọrun àwọn baba wọn mọ́.

33. Josaya run gbogbo àwọn ère oriṣa tí wọ́n wà ní gbogbo ilẹ̀ Israẹli, ó sì mú kí àwọn ọmọ Israẹli sin OLUWA Ọlọrun wọn. Ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀, wọn kò yipada kúrò lẹ́yìn OLUWA Ọlọrun àwọn baba wọn.

Ka pipe ipin Kronika Keji 34