Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kronika Keji 31:3-11 BIBELI MIMỌ (BM)

3. Hesekaya a máa fa ẹran kalẹ̀ ninu agbo ẹran rẹ̀ fún ẹbọ sísun ti àárọ̀ ati ti àṣáálẹ́, ati fún ẹbọ ọjọ́ ìsinmi, ẹbọ oṣù tuntun ati àwọn ẹbọ mìíràn gẹ́gẹ́ bí òfin OLUWA.

4. Ọba pàṣẹ fún àwọn tí wọn ń gbé Jerusalẹmu pé kí wọ́n mú ọrẹ tí ó tọ́ sí àwọn alufaa ati àwọn ọmọ Lefi wa, kí wọ́n lè fi gbogbo àkókò wọn sílẹ̀ láti máa kọ́ àwọn eniyan ní òfin OLUWA.

5. Ní kété tí àṣẹ yìí tàn káàkiri, wọ́n mú ọpọlọpọ àkọ́so ọkà, ati ọtí ati òróró ati oyin, ati àwọn nǹkan irè oko mìíràn wá. Wọ́n tún san ìdámẹ́wàá gbogbo nǹkan tí wọ́n ní.

6. Àwọn ọmọ Israẹli ati ti Juda tí wọn ń gbé àwọn ìlú Juda náà san ìdámẹ́wàá mààlúù ati aguntan, ati ti àwọn ohun mímọ́ tí wọ́n ti yà sọ́tọ̀ fún OLUWA Ọlọrun wọn, wọ́n kó wọn jọ bí òkítì.

7. Ní oṣù kẹta ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí kó àwọn ìdámẹ́wàá náà jọ, wọ́n kó wọn jọ tán ní oṣù keje.

8. Nígbà tí Hesekaya ati àwọn ìjòyè wá wo àwọn ìdámẹ́wàá tí wọ́n kójọ bí òkítì, wọ́n yin OLUWA, wọ́n sì dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn ọmọ Israẹli.

9. Hesekaya bèèrè lọ́wọ́ àwọn alufaa ati àwọn ọmọ Lefi nípa àwọn òkítì náà.

10. Asaraya, olórí alufaa, láti ìdílé Sadoku dá a lóhùn pé: “Láti ìgbà tí àwọn eniyan ti bẹ̀rẹ̀ sí mú ẹ̀bùn wá sí ilé OLUWA ni a ti ń jẹ àjẹyó, tí ó sì ń ṣẹ́kù, nítorí pé OLUWA ti bukun àwọn eniyan rẹ̀, ni a fi ní àjẹṣẹ́kù tí ó pọ̀ tó yìí.”

11. Hesekaya bá pàṣẹ pé kí wọ́n tọ́jú àwọn yàrá tó wà ninu ilé OLUWA, wọ́n bá ṣe ìtọ́jú wọn.

Ka pipe ipin Kronika Keji 31