Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kronika Keji 30:6-20 BIBELI MIMỌ (BM)

6. Àwọn oníṣẹ́ lọ jákèjádò Israẹli ati Juda, pẹlu ìwé láti ọ̀dọ̀ ọba ati àwọn ìjòyè rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí àṣẹ ọba. Wọ́n kọ sinu ìwé náà pé:“Ẹ̀yin eniyan Israẹli, ẹ pada sọ́dọ̀ OLUWA, Ọlọrun Abrahamu, Isaaki, ati Israẹli, kí ó lè pada sọ́dọ̀ ẹ̀yin tí ẹ kù tí ẹ sá àsálà, tí ọba Asiria kò pa.

7. Ẹ má dàbí àwọn baba yín ati àwọn arakunrin yín tí wọ́n ṣe alaiṣootọ sí OLUWA, Ọlọrun àwọn baba wọn, tí ó sì sọ ilẹ̀ wọn di ahoro bí ẹ ti rí i yìí.

8. Ẹ má ṣe oríkunkun, bí àwọn baba yín. Ẹ fi ara yín fún OLUWA, kí ẹ wá sí ibi mímọ́ rẹ̀, tí ó ti yà sọ́tọ̀ títí lae. Ẹ wá sin OLUWA Ọlọrun yín níbẹ̀, kí ibinu rẹ̀ lè yipada kúrò lọ́dọ̀ yín.

9. Bí ẹ bá pada sọ́dọ̀ OLUWA, àwọn arakunrin yín ati àwọn ọmọ yín yóo rí àánú lọ́dọ̀ àwọn tí ó kó wọn lẹ́rú, wọn yóo sì dá wọn pada sí ilẹ̀ yìí. Nítorí olóore ọ̀fẹ́ ati aláàánú ni OLUWA Ọlọrun yín, kò ní kẹ̀yìn si yín bí ẹ bá pada sọ́dọ̀ rẹ̀.”

10. Àwọn oníṣẹ́ ọba lọ láti ìlú kan dé ekeji jákèjádò ilẹ̀ Efuraimu ati ti Manase, títí dé ilẹ̀ Sebuluni. Ṣugbọn àwọn eniyan fi wọ́n rẹ́rìn-ín, wọ́n sì fi wọ́n ṣe ẹlẹ́yà.

11. Àfi díẹ̀ ninu àwọn ará Aṣeri, Manase, ati Sebuluni ni wọ́n rẹ ara wọn sílẹ̀, tí wọ́n wá sí Jerusalẹmu.

12. Ọlọrun lọ́wọ́ sí ohun tí àwọn ará Juda ń ṣe, ó fi sí wọn ní ọkàn láti mú àṣẹ tí ọba ati àwọn olórí pa fún wọn ṣẹ, gẹ́gẹ́ bí àṣẹ OLUWA.

13. Ogunlọ́gọ̀ eniyan péjọ ní Jerusalẹmu ní oṣù keji láti ṣe Àjọ Àìwúkàrà.

14. Wọ́n wó gbogbo pẹpẹ oriṣa ati àwọn pẹpẹ turari tí ó wà ní Jerusalẹmu, wọ́n dà wọ́n sí àfonífojì Kidironi.

15. Wọ́n pa ọ̀dọ́ aguntan Àjọ Ìrékọjá ní ọjọ́ kẹrinla oṣù keji. Ojú ti àwọn alufaa ati àwọn ọmọ Lefi tí wọn kò tíì ya ara wọn sí mímọ́, tóbẹ́ẹ̀ tí wọ́n tètè lọ ya ara wọn sí mímọ́, tí wọ́n sì mú ẹbọ sísun wá sí ilé OLUWA.

16. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí fi ara wọn sí ipò tí ó yẹ kí wọ́n wà, gẹ́gẹ́ bí òfin Mose, eniyan Ọlọrun; àwọn alufaa bẹ̀rẹ̀ sí wọ́n ẹ̀jẹ̀ tí wọ́n gbà lọ́wọ́ àwọn ọmọ Lefi sí orí pẹpẹ.

17. Àwọn tí wọn kò tíì ya ara wọn sí mímọ́ pọ̀ níbi àpéjọ náà, nítorí náà, àwọn ọmọ Lefi bá wọn pa ẹran wọn kí àwọn ẹran náà lè jẹ́ mímọ́ fún OLUWA.

18. Ogunlọ́gọ̀ eniyan, pataki jùlọ ọpọlọpọ ninu àwọn tí wọn wá láti Efuraimu, Manase, Isakari ati Sebuluni, kò tíì ya ara wọn sí mímọ́, sibẹ wọ́n jẹ àsè Àjọ Ìrékọjá, ṣugbọn kì í ṣe ní ọ̀nà ẹ̀tọ́. Ṣugbọn Hesekaya gbadura fún wọn pé: “Kí OLUWA rere dáríjì gbogbo àwọn

19. tí wọ́n fi tọkàntọkàn wá OLUWA Ọlọrun àwọn baba wọn, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó lè má jẹ́ ọ̀nà ẹ̀tọ́ ni wọ́n fi jẹ àsè àjọ náà gẹ́gẹ́ bí òfin ìwẹ̀nùmọ́ ti ibi mímọ́.”

20. OLUWA gbọ́ adura Hesekaya, ó sì wo àwọn eniyan náà sàn.

Ka pipe ipin Kronika Keji 30