Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kronika Keji 29:1-8 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Hesekaya jọba ní Juda nígbà tí ó di ẹni ọdún mẹẹdọgbọn; ó sì wà lórí oyè fún ọdún mọkandinlọgbọn. Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Abija, ọmọ Sakaraya.

2. Ó ṣe ohun tí ó tọ́ lójú OLUWA, gẹ́gẹ́ bí Dafidi baba ńlá rẹ̀ ti ṣe.

3. Ní oṣù kinni ọdún kinni ìjọba rẹ̀, ó ṣí àwọn ìlẹ̀kùn ilé OLUWA, ó sì tún wọn ṣe.

4. Ó kó àwọn alufaa ati àwọn ọmọ Lefi jọ sí gbàgede tí ó wà ní apá ìlà oòrùn ilé Ọlọrun.

5. Ó ní, “Ẹ gbọ́, ẹ̀yin ọmọ Lefi, ẹ ya ara yín sí mímọ́, kí ẹ sì ya ilé OLUWA, Ọlọrun àwọn baba yín sí mímọ́ pẹlu. Ẹ kó gbogbo àwọn nǹkan ẹ̀gbin kúrò ninu ibi mímọ́,

6. nítorí àwọn baba wa ti ṣe aiṣododo, wọ́n sì ṣe nǹkan burúkú lójú OLUWA, Ọlọrun wa. Wọ́n kọ OLUWA sílẹ̀, wọ́n gbójú kúrò lára ibùgbé rẹ̀, wọ́n sì kẹ̀yìn sí i.

7. Wọ́n ti ìlẹ̀kùn yàrá àbáwọlé tẹmpili, wọ́n pa fìtílà tí ó wà ní ibi mímọ́, wọn kò sun turari, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò rú ẹbọ sísun ní ibi mímọ́ sí Ọlọrun Israẹli.

8. Nítorí náà ni OLUWA ṣe bínú sí Juda ati Jerusalẹmu, ohun tí Ọlọrun fi wọ́n ṣe sì dẹ́rùba gbogbo eniyan. Wọ́n di ẹni ẹ̀gàn ati ẹni àrípòṣé, gẹ́gẹ́ bí ẹ ti rí i lónìí.

Ka pipe ipin Kronika Keji 29