Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kronika Keji 25:16-28 BIBELI MIMỌ (BM)

16. Bí wolii yìí ti ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́ ni ọba dá a lóhùn pé, “Panumọ́, ṣé wọ́n fi ọ́ ṣe olùdámọ̀ràn ọba ni? Àbí o fẹ́ kú ni.”Wolii náà bá dákẹ́, ṣugbọn, kí ó tó dákẹ́ ó ní, “Mo mọ̀ pé Ọlọrun ti pinnu láti pa ọ́ run fún ohun tí o ṣe yìí, ati pé, o kò tún fetí sí ìmọ̀ràn mi.”

17. Lẹ́yìn tí Amasaya, ọba Juda, ṣe àpérò pẹlu àwọn olùdámọ̀ràn rẹ̀, ó ranṣẹ sí Jehoaṣi ọmọ Jehoahasi, ọmọ Jehu, ọba Israẹli pé, “Wá, jẹ́ kí á kojú ara wa.”

18. Jehoaṣi ọba Israẹli ranṣẹ sí ọba Juda pé, “Ní àkókò kan, ẹ̀gún ẹ̀wọ̀n kan ní Lẹbanoni ranṣẹ sí igi kedari ní Lẹbanoni pé, ‘Mo fẹ́ fẹ́ ọmọbinrin rẹ fún ọmọkunrin mi.’ Ẹranko ìgbẹ́ kan ń kọjá lọ, ó sì tẹ ẹ̀gún náà mọ́lẹ̀.

19. O bẹ̀rẹ̀ sí fọ́nnu pẹlu ìgbéraga pé o ti ṣẹgun àwọn ará Edomu, ṣugbọn, mo gbà ọ́ ní ìmọ̀ràn pé kí o dúró jẹ́ẹ́ sí ilé rẹ. Kí ló dé tí ò ń fi ọwọ́ ara rẹ fa ìjàngbọ̀n tí ó lè fa ìṣubú ìwọ ati àwọn eniyan rẹ?”

20. Ṣugbọn Amasaya kọ̀, kò gbọ́, nítorí pé Ọlọrun ni ó mú kí ọkàn rẹ̀ le, kí Ọlọrun lè fi Juda lé àwọn ọ̀tá wọn lọ́wọ́ nítorí pé wọ́n ń bọ àwọn oriṣa Edomu.

21. Nítorí náà, Jehoaṣi, ọba Israẹli, gòkè lọ, òun ati Amasaya ọba Juda sì kojú ara wọn lójú ogun ní Beti Ṣemeṣi ní ilẹ̀ Juda.

22. Àwọn ará Israẹli ṣẹgun àwọn ará Juda, olukuluku sì fọ́nká lọ sí ilé rẹ̀.

23. Jehoaṣi, ọba Israẹli mú Amasaya, ọba Juda, ọmọ Joaṣi, ọmọ Ahasaya, ní ojú ogun, ní Beti Ṣemeṣi; ó sì mú un wá sí Jerusalẹmu. Ó wó odi Jerusalẹmu palẹ̀ láti Ẹnubodè Efuraimu títí dé Ẹnubodè Kọ̀rọ̀. Gígùn ibi tí à ń wí yìí jẹ́ irinwo igbọnwọ (200 mita.)

24. Ó kó gbogbo wúrà, fadaka ati àwọn ohun èlò tí ó wà lábẹ́ ìtọ́jú Obedi Edomu ní ilé Ọlọ́run. Lẹ́yìn náà, ó lọ sí ààfin ọba, ó kó gbogbo ìṣúra tí ó wà níbẹ̀ ati àwọn eniyan, ó sì pada sí Samaria.

25. Amasaya, ọmọ Joaṣi, ọba Juda gbé ọdún mẹẹdogun lẹ́yìn ikú Jehoaṣi, ọmọ Jehoahasi, ọba Israẹli.

26. Àkọsílẹ̀ àwọn nǹkan yòókù tí Amasaya ṣe, láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin, wà ninu ìwé àwọn ọba Juda ati Israẹli.

27. Láti ìgbà tí Amasaya ti pada lẹ́yìn OLUWA ni àwọn eniyan ti dìtẹ̀ mọ́ ọn ní Jerusalẹmu, nítorí náà, ó sá lọ sí Lakiṣi. Ṣugbọn wọ́n lépa rẹ̀ lọ sí Lakiṣi, wọ́n sì pa á níbẹ̀.

28. Wọ́n fi ẹṣin gbé òkú rẹ̀ wá sí Jerusalẹmu, wọ́n sì sin ín sí ìlú Dafidi ní ibojì àwọn baba rẹ̀.

Ka pipe ipin Kronika Keji 25