Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kronika Keji 21:11-20 BIBELI MIMỌ (BM)

11. Ó tilẹ̀ kọ́ àwọn pẹpẹ ìrúbọ káàkiri ní agbègbè olókè Juda. Ó fa àwọn ará Jerusalẹmu sinu aiṣododo, ó sì kó àwọn ọmọ Juda ṣìnà.

12. Elija wolii kọ ìwé kan sí Jehoramu, ohun tí ó kọ sinu ìwé náà nìyí: “Gbọ́ bí OLUWA Ọlọrun Dafidi, baba rẹ, ti wí; ó ní, nítorí pé o kò tọ ọ̀nà tí Jehoṣafati baba rẹ tọ̀, tabi ti Asa, baba baba rẹ.

13. Ṣugbọn ò ń hùwà bí àwọn ọba Israẹli, o sì ti fa àwọn Juda ati Jerusalẹmu sinu aiṣododo, bí ìdílé Ahabu ti ṣe fún Israẹli. Pataki jùlọ, o pa àwọn arakunrin rẹ, àwọn ọmọ baba rẹ, tí wọ́n tilẹ̀ sàn jù ọ́ lọ.

14. Wò ó, OLUWA yóo fi àjàkálẹ̀ àrùn ṣe àwọn eniyan rẹ, ati àwọn ọmọ rẹ, ati àwọn aya rẹ ati gbogbo ohun tí o ní.

15. Àrùn burúkú kan yóo kọlu ìwọ pàápàá, àrùn inú ni, yóo pọ̀, yóo sì pẹ́ lára rẹ títí tí ìfun rẹ yóo fi bẹ̀rẹ̀ sí tú jáde.”

16. OLUWA mú kí inú àwọn ará Filistia ati ti àwọn ará Arabia, tí wọn ń gbé nítòsí àwọn ará Etiopia, ru sí Jehoramu.

17. Wọ́n dó ti Juda, wọ́n gbógun tì wọ́n, wọ́n kó gbogbo ìṣúra tí ó wà ní ààfin lọ, pẹlu àwọn ọmọ Jehoramu ati àwọn iyawo rẹ̀. Kò ku ẹyọ ọmọ kan àfi èyí àbíkẹ́yìn tí ń jẹ́ Ahasaya.

18. Lẹ́yìn gbogbo nǹkan wọnyi, OLUWA fi àrùn inú kan tí kò ṣe é wò bá Jehoramu jà.

19. Lẹ́yìn ọdún keji tí àìsàn náà tí ń ṣe é, ìfun rẹ̀ tú síta, ó sì kú ninu ọpọlọpọ ìrora. Wọn kò dá iná ẹ̀yẹ fún un gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti máa ń ṣe níbi ìsìnkú àwọn baba rẹ̀.

20. Ẹni ọdún mejilelọgbọn ni nígbà tí ó gorí oyè, ó sì wà lórí oyè ní Jerusalẹmu fún ọdún mẹjọ. Nígbà tí ó kú, kò sí ẹni tí ó sọkún, tabi tí ó ṣọ̀fọ̀ níbi òkú rẹ̀. Ìlú Dafidi ni wọ́n sin ín sí, ṣugbọn kì í ṣe ní ibojì àwọn ọba.

Ka pipe ipin Kronika Keji 21