Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Joṣua 8:18-33 BIBELI MIMỌ (BM)

18. OLUWA sọ fun Joṣua pé, “Na ọ̀kọ̀ tí ó wà ní ọwọ́ rẹ sí ọ̀kánkán Ai, nítorí n óo fi lé ọ lọ́wọ́.” Joṣua bá na ọ̀kọ̀ ọwọ́ rẹ̀ sí ọ̀kánkán ìlú náà.

19. Gbogbo àwọn tí wọn farapamọ́ bá yára dìde ní ibi tí wọ́n wà. Bí Joṣua ti na ọwọ́ rẹ̀, wọ́n sáré wọ inú ìlú náà, wọ́n gbà á, wọ́n sì yára sọ iná sí i.

20. Nígbà tí àwọn ará Ai bojú wẹ̀yìn, tí wọ́n rí i tí èéfín yọ ní ìlú wọn, wọn kò ní agbára mọ́ láti sá síhìn-ín tabi sọ́hùn-ún, nítorí pé àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n sá gba ọ̀nà aṣálẹ̀ lọ yíjú pada sí wọn.

21. Nígbà tí Joṣua ati àwọn ọmọ Israẹli rí i pé àwọn tí wọn farapamọ́ ti gba ìlú náà, tí èéfín sì ti yọ sókè, wọ́n yipada, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí pa àwọn ará Ai.

22. Àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n wà ninu ìlú náà jáde sí wọn, àwọn ará Ai sì wà ní agbede meji àwọn ọmọ Israẹli, àwọn kan wà ní ẹ̀gbẹ́ kinni, àwọn kan wà ní ẹ̀gbẹ́ keji. Àwọn ọmọ Israẹli bá bẹ̀rẹ̀ sí í pa wọ́n ní ìpakúpa títí tí kò fi ku ẹyọ ẹnìkan.

23. Ṣugbọn wọ́n mú ọba Ai láàyè, wọ́n sì mú un tọ Joṣua wá.

24. Nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli ti fi idà pa gbogbo àwọn ará Ai tán ninu aṣálẹ̀, ní ibi tí wọ́n ti ń lé wọn lọ, wọ́n pada sí ìlú Ai, wọ́n sì fi idà pa gbogbo wọn patapata.

25. Gbogbo àwọn ará Ai tí wọ́n pa ní ọjọ́ náà, ati ọkunrin, ati obinrin, gbogbo wọn jẹ́ ẹgbaafa (12,000).

26. Nítorí pé ọwọ́ tí Joṣua fi na ọ̀kọ̀ sókè, kò gbé e sílẹ̀ títí tí wọ́n fi pa gbogbo àwọn ará Ai tán.

27. Àfi ẹran ọ̀sìn ati dúkìá ìlú náà ni àwọn ọmọ Israẹli kó ní ìkógun gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún Joṣua.

28. Joṣua dáná sun ìlú Ai, ó sì sọ ọ́ di òkítì àlàpà títí di òní olónìí.

29. Ó so ọba Ai kọ́ sórí igi kan títí di ìrọ̀lẹ́, nígbà tí oòrùn ń lọ wọ̀, Joṣua pàṣẹ pé kí wọn já òkú rẹ̀ lulẹ̀, wọ́n sì wọ́ ọ sí ẹnu ọ̀nà bodè ìlú náà, wọ́n kó òkúta jọ lé e lórí, òkúta náà wà níbẹ̀ títí di òní olónìí.

30. Joṣua tẹ́ pẹpẹ kan fún OLUWA Ọlọrun Israẹli ní orí òkè Ebali,

31. bí Mose iranṣẹ OLUWA ti pàṣẹ fún àwọn ọmọ Israẹli ati gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti kọ ọ́ sí inú ìwé òfin Mose pé, “Pẹpẹ tí wọ́n fi òkúta tí wọn kò gbẹ́ kọ́, tí ẹnikẹ́ni kò gbé ohun èlò irin sókè láti gbẹ́ òkúta rẹ̀.” Wọ́n rú ẹbọ sísun ati ẹbọ alaafia sí OLUWA lórí rẹ̀.

32. Joṣua mú òfin tí Mose kọ tẹ́lẹ̀, ó dà á kọ sórí àwọn òkúta náà lójú gbogbo àwọn ọmọ Israẹli.

33. Gbogbo Israẹli, ati onílé, ati àlejò, gbogbo àwọn àgbààgbà, ati àwọn olórí, ati àwọn aṣiwaju dúró ní òdìkejì Àpótí Majẹmu OLUWA, níwájú àwọn alufaa, ọmọ Lefi, tí wọ́n ru Àpótí Majẹmu náà. Ìdajì wọn dúró níwájú òkè Ebali bí Mose, iranṣẹ OLUWA, ti pàṣẹ fún wọn pé kí wọ́n ṣe máa súre fún àwọn ọmọ Israẹli.

Ka pipe ipin Joṣua 8