Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Joṣua 8:12-24 BIBELI MIMỌ (BM)

12. Joṣua ṣa nǹkan bí ẹgbẹẹdọgbọn (5,000) ọmọ ogun, ó fi wọ́n pamọ́ sí ààrin Bẹtẹli ati Ai ní apá ìwọ̀ oòrùn Ai.

13. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe fi àwọn ọmọ ogun wọn sí ipò, àwọn tí wọn yóo gbógun ti ìlú gan-an wà ní apá ìhà àríwá ìlú, àwọn tí wọn yóo wà lẹ́yìn wà ní apá ìwọ̀ oòrùn, ṣugbọn Joṣua alára wà ní àfonífojì ní gbogbo òru ọjọ́ náà.

14. Nígbà tí ọba Ai ati gbogbo àwọn eniyan rẹ̀ rí i, gbogbo àwọn ọkunrin tí wọ́n wà ní ìlú náà bá yára, wọ́n jáde lọ sí gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ apá ọ̀nà Araba láti kó ogun pàdé àwọn ọmọ Israẹli, ṣugbọn wọn kò mọ̀ pé àwọn kan ti farapamọ́ sẹ́yìn ìlú.

15. Joṣua ati gbogbo ọmọ Israẹli tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀ bá ṣe bí ẹni pé àwọn ará Ai ti ṣẹgun àwọn, wọ́n sì sá gba ọ̀nà aṣálẹ̀ lọ.

16. Àwọn ará Ai bá pe gbogbo àwọn eniyan tí wọ́n wà ní ìlú jọ, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí lé àwọn ọmọ Israẹli lọ. Bí wọ́n ti ń lé Joṣua lọ ni wọ́n ń jìnnà sí ìlú.

17. Kò sì sí ẹyọ ọkunrin kan tí ó kù ní Ai ati Bẹtẹli tí kò jáde láti lépa àwọn ọmọ Israẹli. Wọ́n fi ìlẹ̀kùn ẹnubodè sílẹ̀ ní ṣíṣí, wọ́n ń lé àwọn ọmọ Israẹli lọ.

18. OLUWA sọ fun Joṣua pé, “Na ọ̀kọ̀ tí ó wà ní ọwọ́ rẹ sí ọ̀kánkán Ai, nítorí n óo fi lé ọ lọ́wọ́.” Joṣua bá na ọ̀kọ̀ ọwọ́ rẹ̀ sí ọ̀kánkán ìlú náà.

19. Gbogbo àwọn tí wọn farapamọ́ bá yára dìde ní ibi tí wọ́n wà. Bí Joṣua ti na ọwọ́ rẹ̀, wọ́n sáré wọ inú ìlú náà, wọ́n gbà á, wọ́n sì yára sọ iná sí i.

20. Nígbà tí àwọn ará Ai bojú wẹ̀yìn, tí wọ́n rí i tí èéfín yọ ní ìlú wọn, wọn kò ní agbára mọ́ láti sá síhìn-ín tabi sọ́hùn-ún, nítorí pé àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n sá gba ọ̀nà aṣálẹ̀ lọ yíjú pada sí wọn.

21. Nígbà tí Joṣua ati àwọn ọmọ Israẹli rí i pé àwọn tí wọn farapamọ́ ti gba ìlú náà, tí èéfín sì ti yọ sókè, wọ́n yipada, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí pa àwọn ará Ai.

22. Àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n wà ninu ìlú náà jáde sí wọn, àwọn ará Ai sì wà ní agbede meji àwọn ọmọ Israẹli, àwọn kan wà ní ẹ̀gbẹ́ kinni, àwọn kan wà ní ẹ̀gbẹ́ keji. Àwọn ọmọ Israẹli bá bẹ̀rẹ̀ sí í pa wọ́n ní ìpakúpa títí tí kò fi ku ẹyọ ẹnìkan.

23. Ṣugbọn wọ́n mú ọba Ai láàyè, wọ́n sì mú un tọ Joṣua wá.

24. Nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli ti fi idà pa gbogbo àwọn ará Ai tán ninu aṣálẹ̀, ní ibi tí wọ́n ti ń lé wọn lọ, wọ́n pada sí ìlú Ai, wọ́n sì fi idà pa gbogbo wọn patapata.

Ka pipe ipin Joṣua 8