Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Joṣua 4:18-24 BIBELI MIMỌ (BM)

18. Nígbà tí àwọn alufaa tí wọ́n gbé Àpótí Majẹmu OLUWA jáde kúrò ninu odò Jọdani, bí wọ́n ti ń gbé ẹsẹ̀ lé ilẹ̀ gbígbẹ, ni omi odò náà pada sí ààyè rẹ̀. Odò náà sì kún bo gbogbo bèbè rẹ̀, bí ó ti wà tẹ́lẹ̀.

19. Ní ọjọ́ kẹwaa oṣù kinni ni àwọn eniyan náà gun òkè odò Jọdani. Wọ́n pàgọ́ sí Giligali ní ìhà ìlà oòrùn Jẹriko.

20. Joṣua bá to àwọn òkúta mejila tí wọ́n kó jáde láti inú odò Jọdani kalẹ̀ ní Giligali.

21. Ó sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, “Nígbà tí àwọn ọmọ yín bá bèèrè lọ́wọ́ àwọn baba wọn ní ọjọ́ iwájú pé báwo ni ti àwọn òkúta wọnyi ti jẹ́ rí?

22. Ẹ jẹ́ kí àwọn ọmọ yín mọ̀ pé àwọn ọmọ Israẹli kọjá odò Jọdani yìí lórí ilẹ̀ gbígbẹ.

23. Nítorí OLUWA Ọlọrun yín mú kí odò Jọdani gbẹ títí ẹ fi rékọjá sí òdìkejì rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ó ti mú kí Òkun Pupa gbẹ, títí tí ẹ fi là á kọjá.

24. Kí gbogbo aráyé lè mọ̀ pé, OLUWA lágbára, kí ẹ sì lè máa bẹ̀rù OLUWA Ọlọrun yín títí lae.”

Ka pipe ipin Joṣua 4