Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Joṣua 22:3-11 BIBELI MIMỌ (BM)

3. Ẹ kò kọ àwọn arakunrin yín sílẹ̀ láti ọjọ́ yìí wá títí di òní, ṣugbọn ẹ fara balẹ̀, ẹ sì ti ń pa gbogbo àṣẹ OLUWA Ọlọrun yín mọ́.

4. Nisinsinyii, OLUWA Ọlọrun yín ti fún àwọn arakunrin yín ní ìsinmi gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe ìlérí fún wọn; nítorí náà, ẹ pada lọ sí ilẹ̀ yín, níbi tí ohun ìní yín wà, àní ilẹ̀ tí Mose iranṣẹ OLUWA fun yín ní òdìkejì odò Jọdani.

5. Ẹ máa ranti lemọ́lemọ́ láti máa pa gbogbo òfin tí Mose iranṣẹ OLUWA fun yín mọ́, pé kí ẹ fẹ́ràn OLUWA Ọlọrun yín, kí ẹ sì máa rìn ní ọ̀nà rẹ̀, ẹ máa pa gbogbo òfin rẹ̀ mọ́, ẹ súnmọ́ ọn, kí ẹ sì máa sìn ín tọkàntọkàn.”

6. Joṣua bá súre fún wọn, lẹ́yìn náà, ó ní kí wọ́n pada lọ sí ilẹ̀ wọn, wọ́n sì pada lọ.

7. Mose ti kọ́kọ́ fún ìdajì ẹ̀yà Manase ní ilẹ̀ ní Baṣani; Joṣua sì fún ìdajì yòókù ní ilẹ̀ ní ẹ̀gbẹ́ ti àwọn arakunrin wọn, ní ìwọ̀ oòrùn odò Jọdani. Nígbà tí Joṣua rán wọn pada lọ sí ilé wọn, tí ó sì súre fún wọn, ó wí fún wọn pé,

8. “Ẹ máa kó ọpọlọpọ dúkìá pada lọ sí ilé yín, ati ọpọlọpọ ẹran ọ̀sìn, fadaka, wúrà, idẹ, irin, ati ọpọlọpọ aṣọ. Ẹ pín ninu ìkógun tí ẹ kó lọ́dọ̀ àwọn ọ̀tá yín fún àwọn arakunrin yín.”

9. Nítorí náà àwọn ẹ̀yà Reubẹni, ẹ̀yà Gadi ati ìdajì ẹ̀yà Manase fi àwọn ọmọ Israẹli yòókù sílẹ̀ ní Ṣilo, tí ó wà ní ilẹ̀ Kenaani, wọ́n sì pada lọ sí ilẹ̀ Gileadi tí í ṣe ilẹ̀ tiwọn tí wọ́n pín fún wọn, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ láti ẹnu Mose.

10. Nígbà tí wọ́n dé agbègbè odò Jọdani, tí ó wà ní ilẹ̀ Kenaani, àwọn ẹ̀yà Reubẹni, ẹ̀yà Gadi, ati ìdajì ẹ̀yà Manase tẹ́ pẹpẹ kan lẹ́bàá Jọdani, pẹpẹ náà tóbi pupọ.

11. Nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli gbọ́ pé àwọn ẹ̀yà Reubẹni, ẹ̀yà Gadi ati ìdajì ẹ̀yà Manase ti tẹ́ pẹpẹ kan sí ìhà ibi tí ó jẹ́ ti àwọn ọmọ Israẹli, ní agbègbè odò Jọdani, ní àtiwọ ilẹ̀ Kenaani,

Ka pipe ipin Joṣua 22