Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Joṣua 20:6-9 BIBELI MIMỌ (BM)

6. Ìlú yìí ni yóo máa gbé títí tí àwọn ìgbìmọ̀ yóo fi ṣe ìdájọ́ rẹ̀, yóo máa gbé ibẹ̀ títí tí ẹni tí ó jẹ́ olórí alufaa ní àkókò náà yóo fi kú, lẹ́yìn náà ẹni tí ó ṣèèṣì pa eniyan yìí lè pada lọ sí ilé rẹ̀ ati sí ìlú rẹ̀ níbi tí ó ti sá wá.”

7. Wọ́n ya Kedeṣi sọ́tọ̀ ní Galili ní agbègbè olókè ti Nafutali, ati Ṣekemu ní agbègbè olókè ti Efuraimu, ati Kiriati Ariba (tí wọ́n ń pè ní Heburoni), ní agbègbè olókè ti Juda.

8. Ní òdìkejì odò Jọdani, ní apá ìlà oòrùn Jẹriko, wọ́n ya Beseri tí ó wà ninu aṣálẹ̀ ní ilẹ̀ tí ó tẹ́jú sọ́tọ̀. Wọ́n ya Ramoti tí ó wà ní Gileadi sọ́tọ̀ ní agbègbè ti ẹ̀yà Gadi, ati Golani tí ó wà ní Baṣani, ní agbègbè ti ẹ̀yà Manase.

9. Àwọn ìlú ọ̀hún ni ìlú ààbò tí wọ́n yàn fún àwọn ọmọ Israẹli, ati fún àwọn àlejò tí wọ́n ń gbé ààrin wọn. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣèèṣì pa eniyan lè sá lọ sí èyíkéyìí ninu wọn, yóo sì bọ́ lọ́wọ́ ẹni tí ń gbẹ̀san ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ títí tí àwọn ìgbìmọ̀ yóo fi ṣe ìdájọ́ rẹ̀.

Ka pipe ipin Joṣua 20