Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Joṣua 18:1-11 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Lẹ́yìn tí àwọn ọmọ Israẹli ti ṣẹgun ilẹ̀ náà, gbogbo wọn péjọ sí Ṣilo, wọ́n sì pa àgọ́ àjọ níbẹ̀.

2. Ó ku ẹ̀yà meje, ninu àwọn ẹ̀yà Israẹli, tí wọn kò tíì pín ilẹ̀ fún.

3. Joṣua bá sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, “Ìgbà wo ni ẹ fẹ́ dúró dà kí ẹ tó lọ gba ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun àwọn baba yín ti fun yín.

4. Ẹ yan eniyan mẹta mẹta wá láti inú ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan, n óo sì rán wọn jáde lọ láti rin ilẹ̀ náà jákèjádò, kí wọ́n lè ṣe àkọsílẹ̀ ibi tí wọ́n bá fẹ́ gẹ́gẹ́ bí ìpín tiwọn, lẹ́yìn náà, kí wọ́n pada wá jíyìn fún mi.

5. Ọ̀nà meje ni wọn yóo pín ilẹ̀ náà sí, àwọn ẹ̀yà Juda kò ní kúrò ní àyè tiwọn ní apá ìhà gúsù, bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn ẹ̀yà Josẹfu tí wọ́n wà ní agbègbè tiwọn ní apá ìhà àríwá.

6. Ẹ óo ṣe àkọsílẹ̀ ìpín mejeeje, ẹ óo sì mú un tọ̀ mí wá. N óo ba yín ṣẹ́ gègé lórí wọn níhìn-ín, níwájú OLUWA Ọlọrun wa.

7. Àwọn ẹ̀yà Lefi kò ní ba yín pín ilẹ̀ nítorí iṣẹ́ alufaa OLUWA ni ìpín tiwọn. Ẹ̀yà Gadi ati ti Reubẹni ati ìdajì ẹ̀yà Manase ti gba ìpín tiwọn tí Mose, iranṣẹ OLUWA, fún wọn ní apá ìlà oòrùn, ní òdìkejì odò Jọdani.”

8. Àwọn ọkunrin náà bẹ̀rẹ̀ ìrìn àjò wọn, Joṣua sì kìlọ̀ fún wọn, pé, “Ẹ rin ilẹ̀ náà jákèjádò, kí ẹ sì kọ àpèjúwe rẹ̀ sílẹ̀ wá fún mi. N óo sì ba yín ṣẹ́ gègé níhìn-ín níwájú OLUWA ní Ṣilo.” Àwọn ọkunrin náà bá lọ,

9. wọ́n rin ilẹ̀ náà jákèjádò, wọ́n sì ṣe àkọsílẹ̀ àpèjúwe àwọn ìlú tí wọ́n wà ninu rẹ̀ ní ìsọ̀rí meje sinu ìwé kan, wọ́n pada wá sí ọ̀dọ̀ Joṣua ninu àgọ́ ní Ṣilo.

10. Joṣua bá bá wọn ṣẹ́ gègé ní Ṣilo, níwájú OLUWA, bẹ́ẹ̀ ni Joṣua ṣe pín ilẹ̀ fún àwọn ọmọ Israẹli. Ó fún ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan ní ìpín tirẹ̀.

11. Ìpín ti ẹ̀yà Bẹnjamini gẹ́gẹ́ bí iye ìdílé wọn wà ní ààrin ilẹ̀ ẹ̀yà Juda ati ti ẹ̀yà Josẹfu.

Ka pipe ipin Joṣua 18