Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Joṣua 10:1-9 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Nígbà tí Adonisedeki, ọba Jerusalẹmu, gbọ́ bí Joṣua ṣe gba ìlú Ai, ati pé ó pa ìlú Ai ati ọba rẹ̀ run, bí ó ti ṣe sí ìlú Jẹriko ati ọba rẹ̀; ati pé àwọn ará Gibeoni ti bá àwọn ọmọ Israẹli dá majẹmu alaafia, wọ́n sì ń gbé ààrin wọn,

2. ẹ̀rù bà á gidigidi, nítorí pé ìlú ńlá ni ìlú Gibeoni bí ọ̀kan ninu àwọn ìlú ọba aládé. Gibeoni tóbi ju ìlú Ai lọ, akọni sì ni gbogbo àwọn ọkunrin ibẹ̀.

3. Nítorí náà, Adonisedeki ọba Jerusalẹmu ranṣẹ sí Hohamu ọba Heburoni, Piramu ọba Jarimutu, Jafia ọba Lakiṣi ati Debiri ọba Egiloni, pé,

4. “Ẹ wá ràn mí lọ́wọ́. Ẹ jẹ́ kí á kọlu Gibeoni, nítorí pé ó ti bá Joṣua ati àwọn ọmọ Israẹli dá majẹmu alaafia.”

5. Nígbà náà ni àwọn ọba Amori maraarun, ọba Jerusalẹmu, ti Heburoni, ti Jarimutu, ti Lakiṣi, ati ti Egiloni parapọ̀, wọ́n kó gbogbo àwọn ọmọ ogun wọn jọ. Wọ́n lọ dó ti Gibeoni, wọ́n sì ń bá a jagun.

6. Àwọn ará Gibeoni bá ranṣẹ sí Joṣua ní àgọ́ tí ó wà ní Giligali. Wọ́n ní, “Ẹ má fi àwa iranṣẹ yín sílẹ̀! Ẹ tètè yára wá gbà wá kalẹ̀, ẹ wá ràn wá lọ́wọ́. Nítorí pé, gbogbo àwọn ọba Amori, tí wọn ń gbé agbègbè olókè, ti kó ara wọn jọ sí wa.”

7. Joṣua bá lọ láti Giligali, òun ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀, pẹlu gbogbo àwọn tí wọ́n jẹ́ akikanju ati akọni.

8. OLUWA wí fún Joṣua pé, “Má bẹ̀rù wọn, nítorí pé mo ti fi wọ́n lé ọ lọ́wọ́. Ẹnikẹ́ni ninu wọn kò ní lè ṣẹgun rẹ.”

9. Joṣua jálù wọ́n lójijì, lẹ́yìn tí ó ti fi gbogbo òru rìn láti Giligali.

Ka pipe ipin Joṣua 10