Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Joṣua 1:9-17 BIBELI MIMỌ (BM)

9. Ranti pé mo ti pàṣẹ fún ọ pé kí o múra, kí o sì ṣe ọkàn gírí. Má bẹ̀rù, má sì jẹ́ kí ìrẹ̀wẹ̀sì bá ọkàn rẹ, nítorí pé èmi, OLUWA Ọlọrun rẹ wà pẹlu rẹ níbikíbi tí o bá ń lọ.”

10. Lẹ́yìn náà, Joṣua pàṣẹ fún gbogbo àwọn olórí àwọn eniyan náà, ó ní,

11. “Ẹ lọ káàkiri ibùdó, kí ẹ sì pàṣẹ fún àwọn eniyan náà, pé kí wọn máa pèsè oúnjẹ sílẹ̀, nítorí pé láàrin ọjọ́ mẹta wọn óo la odò Jọdani kọjá láti lọ gba ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun wọn fún wọn.”

12. Joṣua sọ fún àwọn ẹ̀yà Reubẹni, ati ti Gadi, ati ìdajì ẹ̀yà Manase pé,

13. “Ẹ ranti àṣẹ tí Mose, iranṣẹ OLUWA, pa fun yín pé, ‘OLUWA Ọlọrun yín ń pèsè ibi ìsinmi fun yín, yóo sì fi ilẹ̀ yìí fun yín.’

14. Àwọn aya yín, àwọn ọmọ yín kéékèèké, ati àwọn ẹran ọ̀sìn yín ni yóo kù lẹ́yìn lórí ilẹ̀ tí Mose fun yín ní òdìkejì odò Jọdani; ṣugbọn gbogbo àwọn akọni láàrin yín yóo rékọjá sí òdìkejì odò náà pẹlu ihamọra ogun níwájú àwọn arakunrin yín, wọn yóo máa ràn wọ́n lọ́wọ́

15. títí tí OLUWA yóo fi fún àwọn arakunrin yín ní ìsinmi gẹ́gẹ́ bí ó ti fun yín, tí wọn yóo sì fi gba ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun yín yóo fún wọn. Nígbà náà ni ẹ óo tó pada sí orí ilẹ̀ yín, tí Mose, iranṣẹ OLUWA, fun yín ní ìhà ìlà oòrùn odò Jọdani, ẹ óo sì máa gbé ibẹ̀.”

16. Wọ́n dá Joṣua lóhùn pé, “Gbogbo ohun tí o pa láṣẹ fún wa ni a óo ṣe, ibikíbi tí o bá sì rán wa ni a óo lọ.

17. Bí a ti gbọ́ ti Mose, bẹ́ẹ̀ ni a óo máa gbọ́ tìrẹ náà. Kí OLUWA Ọlọrun rẹ ṣá ti wà pẹlu rẹ gẹ́gẹ́ bí ó ti wà pẹlu Mose.

Ka pipe ipin Joṣua 1