Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Joẹli 1:13-19 BIBELI MIMỌ (BM)

13. Ẹ wọ aṣọ ọ̀fọ̀, kí ẹ sì sọkún, ẹ̀yin alufaa,ẹ sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn,ẹ̀yin tí ẹ̀ ǹ ṣiṣẹ́ ní ibi pẹpẹ ìrúbọ.Ẹ̀yin òjíṣẹ́ Ọlọrun mi, ẹ wọlé,kí ẹ sì fi aṣọ ọ̀fọ̀ bora sùn,nítorí a ti dáwọ́ ẹbọ ohun jíjẹ ati ẹbọ ohun mímu dúró ní ilé Ọlọrun yín.

14. Ẹ kéde ààwẹ̀, kí ẹ sì pe àpèjọ.Ẹ pe àwọn àgbààgbà, ati gbogbo àwọn tí ń gbé ilẹ̀ náà jọ sí ilé OLUWA Ọlọrun yín,kí ẹ sì kígbe pe OLUWA.

15. Ó ṣe! Ọjọ́ náà ń bọ̀,ọjọ́ OLUWA dé tán!Ọjọ́ náà yóo dé bí ọjọ́ ìparun láti ọ̀dọ̀ Olodumare.

16. A ti gba oúnjẹ lẹ́nu yín, níṣojú yín,bẹ́ẹ̀ ni a gba ayọ̀ ati inú dídùn kúrò ní ilé Ọlọrun wa.

17. Irúgbìn díbàjẹ́ sinu ebè,àwọn ilé ìṣúra ti di ahoro,àwọn àká ti wó lulẹ̀,nítorí kò sí ọkà láti kó sinu wọn mọ́.

18. Àwọn ẹran ọ̀sìn ń kérora,àwọn agbo mààlúù dààmú,nítorí pé kò sí pápá oko fún wọn;àwọn agbo aguntan pàápàá dààmú.

19. Ìwọ ni mo kígbe pè, OLUWA,nítorí iná ti jó gbogbo pápá oko run,ó sì ti jó gbogbo igi oko run.

Ka pipe ipin Joẹli 1