Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremaya 51:7-20 BIBELI MIMỌ (BM)

7. Ife wúrà ni Babiloni jẹ́ lọ́wọ́ OLUWA,ó ń pa gbogbo ayé bí ọtí;àwọn orílẹ̀-èdè mu ninu ọtí rẹ̀,wọ́n sì ń ta gbọ̀n-ọ́n-gbọ̀n-ọ́n.

8. Babiloni ṣubú lójijì, ó sì fọ́;ẹ sun ẹkún arò nítorí rẹ̀!Ẹ fi ìwọ̀ra pa á lára nítorí ìrora rẹ̀,bóyá ara rẹ̀ yóo yá.

9. À bá wo Babiloni sàn,ṣugbọn a kò rí i wòsàn.Ẹ pa á tì, ẹ jẹ́ kí á lọ,kí olukuluku máa lọ sí ilẹ̀ rẹ̀;nítorí ẹjọ́ tí a dá a ti dé òkè ọ̀run,a sì ti gbé e sókè dé ojú ọ̀run.”

10. OLUWA ti dá wa láre;ẹ wá, ẹ jẹ́ kí á lọ ròyìn iṣẹ́ OLUWA Ọlọrun wa ní Sioni.

11. Ẹ pọ́n ọfà yín!Ẹ gbé asà yín!Nítorí OLUWA ti ru ẹ̀mí àwọn ọba Media sókè,nítorí pé ó ti pinnu láti pa Babiloni run.Ẹ̀san OLUWA ni, ẹ̀san nítorí tẹmpili rẹ̀ tí wọ́n wó.

12. Ẹ gbé àsíá kan sókè, ẹ gbé e ti odi Babiloni;ẹ ṣe ìsénà tí ó lágbára.Ẹ fi àwọn aṣọ́nà sí ipò wọn;ẹ dira fún àwọn kan, kí wọn sápamọ́,nítorí OLUWA ti pinnu, ó sì ti ṣe ohun tí ó sọ nípa àwọn ará Babiloni.

13. Ìwọ Babiloni, tí odò yí ká,tí ìṣúra rẹ pọ̀ lọpọlọpọ,òpin ti dé bá ọ,okùn tí ó so ayé rẹ rọ̀ ti já.

14. OLUWA àwọn ọmọ ogun ti fi ara rẹ̀ búra,pé òun yóo mú kí àwọn eniyan kún inú rẹ bí eṣú,wọn yóo sì kígbe ìṣẹ́gun lé ọ lórí.

15. OLUWA ni ó fi agbára rẹ̀ dá ilé ayé,tí ó fi ìdí ayé múlẹ̀ pẹlu ìmọ̀ rẹ̀,ó sì fi òye rẹ̀ ta àwọn ọ̀run bí aṣọ.

16. Nígbà tí ó bá sọ̀rọ̀,ojú ọ̀run yóo kún fún alagbalúgbú omi,ó sì ń mú ìkùukùu gòkè láti òpin ilẹ̀ ayé.Ó dá mànàmáná fún òjò,ó sì mú ìjì jáde láti inú ilé ìṣúra rẹ̀.

17. Òmùgọ̀ ni gbogbo eniyan, wọn kò sì ní ìmọ̀,gbogbo alágbẹ̀dẹ wúrà sì gba ìtìjú lórí oriṣa tí wọn dà;nítorí pé irọ́ ni ère tí wọ́n rọ,wọn kò ní èémí.

18. Asán ni wọ́n, wọ́n ń ṣini lọ́nà,píparun ni wọn yóo parun, ní ọjọ́ ìjìyà wọn.

19. Ọlọrun ti Jakọbu kò dàbí àwọn wọnyi,nítorí pé òun ní ẹlẹ́dàá ohun gbogbo;ẹ̀yà Israẹli ni eniyan tirẹ̀,OLUWA àwọn ọmọ ogun sì ni orúkọ rẹ̀.OLUWA sọ fún Babiloni pé,

20. “Ìwọ ni òòlù ati ohun ìjà mi:ìwọ ni mo fi wó àwọn orílẹ̀-èdè wómúwómú,ìwọ ni mo sì fi pa àwọn ìjọba run.

Ka pipe ipin Jeremaya 51