Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremaya 50:17-30 BIBELI MIMỌ (BM)

17. OLUWA ní, “Israẹli dàbí aguntan tí àwọn kinniun ń lé kiri. Ọba Asiria ni ó kọ́kọ́ fi ṣe ẹran ìjẹ, ọba Babiloni sì ń wó àwọn egungun rẹ̀ tí ó kù.

18. Nítorí náà èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli, ni mo sọ pé n óo jẹ ọba Babiloni ati ilẹ̀ rẹ̀ níyà, bí mo ṣe jẹ ọba Asiria níyà.

19. N óo mú Israẹli pada sí ibùjẹ rẹ̀, yóo máa jẹ oúnjẹ tí ó bá hù lórí òkè Kamẹli ati ní agbègbè Baṣani, yóo sì tẹ́ ìfẹ́ ọkàn rẹ̀ lọ́rùn lórí òkè Efuraimu ati òkè Gileadi.

20. OLUWA ní, Nígbà tí ó bá yá, tí àkókò bá tó, a óo wá ẹ̀ṣẹ̀ tì ní Israẹli ati Juda; nítorí pé n óo dáríjì àwọn tí mo bá ṣẹ́kù.”

21. OLUWA ní,“Ẹ gbógun ti ilẹ̀ Merataimu, ati àwọn ará Pekodi.Ẹ pa wọ́n, kí ẹ sì run wọ́n patapata.Gbogbo nǹkan tí mo pàṣẹ fun yín ni kí ẹ ṣe.Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.

22. A gbọ́ ariwo ogun ati ìparun ńlá, ní ilẹ̀ náà.

23. Ẹ wo bí a ti gé òòlù tó ti ń lu gbogbo ayé lulẹ̀,tí a sì fọ́ ọ!Ẹ wo bí Babiloni ti di ohun àríbẹ̀rù, láàrin àwọn orílẹ̀-èdè.

24. Mo dẹ tàkúté sílẹ̀ fun yín, ẹ̀yin ará Babiloni:Tàkúté náà mu yín, ẹ kò sì mọ̀.Wọ́n ri yín, ọwọ́ sì tẹ̀ yín,nítorí pé ẹ yájú sí èmi OLUWA.

25. Mo ti ṣí ìlẹ̀kùn ilé ìṣúra àwọn nǹkan ìjà yín,mo sì kó àwọn ohun ìjà ibinu yín jáde,nítorí èmi OLUWA Ọlọrun àwọn ọmọ ogun ní iṣẹ́ kan láti ṣe ní ilẹ̀ àwọn ará Kalidea.

26. Ẹ gbógun tì í ní gbogbo ọ̀nà,ẹ ṣí àká rẹ̀ sílẹ̀,ẹ kó o jọ bí òkítì ọkà,kí ẹ sì pa á run patapata,ẹ má dá ohunkohun sí ninu rẹ̀.

27. Ẹ pa gbogbo akọ mààlúù rẹ̀,ẹ fà wọ́n lọ sí ibi tí wọ́n ti ń pa ẹran.Àwọn ará Babiloni gbé, nítorí ọjọ́ wọn ti pé,àní ọjọ́ ìjìyà wọn.”

28. (Ẹ gbọ́ ariwo bí àwọn eniyan tí ń sá àsálà kúrò ní ilẹ̀ Babiloni, wá sí Sioni, láti wá ròyìn ìgbẹ̀san Ọlọrun wa, ẹ̀san tẹmpili rẹ̀ tí wọ́n wó lulẹ̀.)

29. “Ẹ pe àwọn tafàtafà jọ, kí wọn dojú kọ Babiloni; kí gbogbo àwọn tí wọn ń tafà pàgọ́ yí i ká, kí wọn má jẹ́ kí ẹnikẹ́ni sá àsálà. Ẹ san án fún un gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀, ẹ ṣe sí i bí ó ti ṣe sí àwọn ẹlòmíràn; nítorí pé ó ṣe àfojúdi sí OLUWA, Ẹni Mímọ́ Israẹli.

30. Nítorí náà àwọn ọdọmọkunrin rẹ̀, yóo kú ní gbàgede rẹ̀. Gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀ ní a óo parun ní ọjọ́ náà. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.

Ka pipe ipin Jeremaya 50