Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremaya 49:26-39 BIBELI MIMỌ (BM)

26. Àwọn ọdọmọkunrin Damasku yóo ṣubú ní gbàgede rẹ̀ ní ọjọ́ náà,gbogbo àwọn ọmọ ogun ibẹ̀ yóo sì parun ni;Èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.

27. N óo dáná sun odi Damasku,yóo sì jó ibi ààbò Benhadadi.”

28. OLUWA sọ nípa Kedari ati àwọn ìjọba Hasori tí Nebukadinesari ọba Babiloni ṣẹgun pé,“Ẹ dìde kí ẹ gbógun ti Kedari!Ẹ pa àwọn ará ìlà oòrùn run!

29. Ogun yóo kó àgọ́ wọn ati àwọn ẹran ọ̀sìn wọn lọ,ati àwọn aṣọ àgọ́, ati ohun ìní wọn;Ọ̀tá yóo kó ràkúnmí wọn lọ,àwọn eniyan yóo máa kígbe sí wọn pé,‘Ìpayà wà ní gbogbo àyíká.’

30. “Ẹ̀yin ará Hasori, ẹ sá,ẹ lọ jìnnà réré, kí ẹ sì máa gbé inú ọ̀gbun.Nítorí pé Nebukadinesari, ọba Babiloni ń pète ibi si yín,ó ti pinnu ibi si yín.

31. Ó ní, ‘Ẹ dìde kí ẹ gbógun ti orílẹ̀-èdè tí ó wà ní alaafia, ati láìléwu,ìlú tí ó dá dúró tí kò sì ní ìlẹ̀kùn tabi ọ̀pá ìdábùú ìlẹ̀kùn fún ààbò.’

32. “Àwọn ràkúnmí ati agbo ẹran wọn yóo di ìkógun.N óo fọ́n àwọn tí wọn ń gé ẹsẹ̀ irun wọn ká sí igun mẹrẹẹrin ayé,n óo sì mú kí ibi bá wọn láti gbogbo àyíká wọn.

33. Hasori yóo di ibùgbé ajáko,yóo di ahoro títí laelae.Ẹnìkan kò ní gbé ibẹ̀ mọ́,bẹ́ẹ̀ ni ẹnikẹ́ni kò ní dé sibẹ mọ́.”

34. OLUWA àwọn ọmọ ogun bá Jeremaya wolii sọ nípa Elamu ní ìbẹ̀rẹ̀ ìjọba Sedekaya, ọba Juda.

35. Ó ní, “Wò ó! N óo pa àwọn tafàtafà Elamu, tí wọn jẹ́ orísun agbára wọn,

36. n óo mú kí ẹ̀fúùfù mẹrin láti igun mẹrẹẹrin ojú ọ̀run kọlu Elamu; n óo sì fọ́n wọn ká sinu ẹ̀fúùfù náà, kò sì ní sí orílẹ̀-èdè kan tí àwọn ará Elamu kò ní fọ́n ká dé.

37. N óo dẹ́rùbà wọ́n; níwájú àwọn ọ̀tá wọn, ati níwájú àwọn tí ń wá ọ̀nà ati pa wọ́n. N óo bínú sí wọn gan-an, n óo sì mú kí ibi dé bá wọn. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀. N óo rán ogun tẹ̀lé wọn, títí n óo fi pa wọ́n tán.

38. N óo tẹ́ ìtẹ́ mi kalẹ̀ ní Elamu, n óo sì pa ọba ati àwọn ìjòyè wọn.

39. Ṣugbọn nígbẹ̀yìn, n óo dá ire Elamu pada. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”

Ka pipe ipin Jeremaya 49