Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremaya 49:18-29 BIBELI MIMỌ (BM)

18. Yóo rí fún un bí ó ti rí fún Sodomu ati Gomora ati àwọn ìlú agbègbè wọn tí ó parun. Ẹnikẹ́ni kò ní gbé ibẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ẹnikẹ́ni kò ní dé sibẹ. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.

19. Wò ó, bí kinniun tií yọ ní aginjù odò Jọdani láti kọlu agbo aguntan, bẹ́ẹ̀ ni n óo yọ sí Edomu n óo sì mú kí ó sá kúrò lórí ilẹ̀ rẹ̀ lójijì. N óo sì yan ẹnikẹ́ni tí ó bá wù mí láti máa ṣe àkóso ibẹ̀; nítorí ta ló dàbí mi? Ta ló lè yẹ̀ mí lọ́wọ́ wò? Olùṣọ́-aguntan wo ló lè dúró dè mí?

20. Nítorí náà, ẹ gbọ́ ète tí OLUWA pa lórí Edomu, ati èrò rẹ̀ lórí àwọn tí wọn ń gbé Temani. A óo kó agbo ẹran wọn lọ tọmọtọmọ, ibùjẹ àwọn ẹran wọn yóo parun nítorí tiwọn.

21. Ariwo wíwó odi Edomu wọn yóo mi ilẹ̀ tìtì, a óo sì gbọ́ ìró rẹ̀ títí dé etí òkun pupa.

22. Wò ó! Ẹnìkan yóo fò bí ẹyẹ idì, yóo na ìyẹ́ rẹ̀ sórí Bosira, ní ọjọ́ náà ọkàn àwọn ọmọ ogun Edomu yóo dàbí ọkàn obinrin tí ń rọbí.”

23. Ohun tí OLUWA sọ nípa Damasku nìyí, Ó ní,“Ìdààmú dé bá Hamati ati Aripadi,nítorí pé wọ́n gbọ́ ìròyìn burúkú:Jìnnìjìnnì dà bò wọ́n, ọkàn wọn sì dàrú,bí omi òkun tí kò lè dákẹ́ jẹ́ẹ́.

24. Àárẹ̀ mú Damasku,ó pẹ̀yìndà pé kí ó máa sálọ,ṣugbọn ìpayà mú un,ìrora ati ìbànújẹ́ sì dé bá a, bí obinrin tí ń rọbí.

25. Ẹ wò ó bí ìlú olókìkí tí ó kún fún ayọ̀, ṣe di ibi ìkọ̀sílẹ̀!

26. Àwọn ọdọmọkunrin Damasku yóo ṣubú ní gbàgede rẹ̀ ní ọjọ́ náà,gbogbo àwọn ọmọ ogun ibẹ̀ yóo sì parun ni;Èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.

27. N óo dáná sun odi Damasku,yóo sì jó ibi ààbò Benhadadi.”

28. OLUWA sọ nípa Kedari ati àwọn ìjọba Hasori tí Nebukadinesari ọba Babiloni ṣẹgun pé,“Ẹ dìde kí ẹ gbógun ti Kedari!Ẹ pa àwọn ará ìlà oòrùn run!

29. Ogun yóo kó àgọ́ wọn ati àwọn ẹran ọ̀sìn wọn lọ,ati àwọn aṣọ àgọ́, ati ohun ìní wọn;Ọ̀tá yóo kó ràkúnmí wọn lọ,àwọn eniyan yóo máa kígbe sí wọn pé,‘Ìpayà wà ní gbogbo àyíká.’

Ka pipe ipin Jeremaya 49