Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremaya 48:30-41 BIBELI MIMỌ (BM)

30. Mo mọ̀ pé aláfojúdi ni.Ó ń fọ́nnu lásán ni, kò lè ṣe nǹkankan tó yanjú.

31. Nítorí náà, ni mo ṣe ń sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn, tí mò ń kígbe sókè nítorí Moabutí mo sì ń ṣọ̀fọ̀ nítorí àwọn ará Kiri Heresi.

32. Ìwọ ọgbà àjàrà Sibima,ọ̀rọ̀ rẹ pa mí lẹ́kún, ju ti Jaseri lọ!Àwọn ẹ̀ka rẹ tàn dé òkun, wọ́n tàn títí dé Jaseri,apanirun sì ti kọlu àwọn èso ẹ̀ẹ̀rùn rẹ, ati èso àjàrà rẹ.

33. Wọ́n ti mú ayọ̀ ati ìdùnnú kúrò ní ilẹ̀ ọlọ́ràá Moabu;mo ti mú kí ọtí waini tán níbi tí wọ́n ti ń ṣe é,kò sí ẹni tí ó ń ṣe ọtí waini pẹlu ariwo ayọ̀ mọ́, ariwo tí wọn ń pa kì í ṣe ti ayọ̀.

34. “Heṣiboni ati Eleale kígbe sókè, igbe wọn sì dé Jahasi láti Soari, ó dé Horonaimu ati Egilati Ṣeliṣiya. Àwọn odò Nimrimu pàápàá ti gbẹ.

35. N óo pa àwọn tí ń rú ẹbọ níbi pẹpẹ ìrúbọ run, ati àwọn tí ń sun turari sí oriṣa ní ilẹ̀ Moabu.

36. “Nítorí náà ni mo ṣe ń dárò Moabu ati àwọn ará Kiri Heresi bí ẹni fi fèrè kọ orin arò nítorí pé gbogbo ọrọ̀ tí wọ́n kó jọ ti ṣègbé.

37. Gbogbo wọn ti fá irun orí ati irùngbọ̀n wọn; wọ́n ti fi abẹ ya gbogbo ọwọ́ wọn, wọ́n sì lọ́ aṣọ ọ̀fọ̀ mọ́ ìbàdí.

38. Gbogbo eniyan ń sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn ní gbogbo orí ilé Moabu, ati àwọn ìta gbangba rẹ̀. Nítorí pé mo ti fọ́ Moabu, bíi ohun èlò tí ẹnikẹ́ni kò bìkítà fún. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.

39. A ti fọ́ Moabu túútúú! Ẹ̀ ń sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn! Moabu pẹ̀yìndà pẹlu ìtìjú! Moabu wá di ẹni yẹ̀yẹ́ ati ẹni àríbẹ̀rù fún gbogbo àwọn tí wọ́n yí i ká.”

40. OLUWA ní,“Wò ó, ẹnìkan yóo fò wá bí ẹyẹ idì,yóo sì na ìyẹ́ apá rẹ̀ lé Moabu lórí.

41. Ogun yóo kó àwọn ìlú Moabu,wọn óo sì gba àwọn ibi ààbò rẹ̀.Ní ọjọ́ náà, ọkàn àwọn ọmọ ogun Moabu yóo dàbí ọkàn obinrin tí ó ń rọbí,

Ka pipe ipin Jeremaya 48