orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14
  15. 15
  16. 16
  17. 17
  18. 18
  19. 19
  20. 20
  21. 21
  22. 22
  23. 23
  24. 24
  25. 25
  26. 26
  27. 27
  28. 28
  29. 29
  30. 30
  31. 31
  32. 32
  33. 33
  34. 34
  35. 35
  36. 36
  37. 37
  38. 38
  39. 39
  40. 40
  41. 41
  42. 42
  43. 43
  44. 44
  45. 45
  46. 46
  47. 47
  48. 48
  49. 49
  50. 50
  51. 51
  52. 52

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremaya 47 BIBELI MIMỌ (BM)

Iṣẹ́ tí OLUWA Rán sí Àwọn Ará Filistia

1. OLUWA bá Jeremaya wolii sọ̀rọ̀ nípa Filistini kí Farao tó ṣẹgun Gasa,

2. Ó ní,“Wò ó, omi kan ń ru bọ̀ láti ìhà àríwá,yóo di àgbàrá tí ó lágbára;yóo ya bo ilẹ̀ yìí ati gbogbo ohun tí ó wà lórí rẹ̀,yóo ya bo ìlú yìí pẹlu, ati àwọn tí wọn ń gbé inú rẹ̀.Àwọn eniyan yóo kígbe: gbogbo àwọn ará ìlú yóo sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn.

3. Nígbà tí pátákò ẹsẹ̀ ẹṣin bá ń dún,tí àwọn kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ bá ń sáré,tí ẹsẹ̀ àwọn kẹ̀kẹ́ ogun sì ń pariwo,Àwọn baba kò ní lè wo àwọn ọmọ wọn lẹ́yìn pé kí àwọn fà wọ́n,nítorí pé ọwọ́ wọn yóo rọ;

4. nítorí ọjọ́ tí ń bọ̀, tí yóo jẹ́ ọjọ́ ìparun gbogbo àwọn ará Filistia,ọjọ́ tí a óo run gbogbo àwọn olùrànlọ́wọ́ tí ó kù fún Tire ati Sidoni.Nítorí pé OLUWA yóo pa àwọn ará Filistia run,àwọn tí wọ́n kù ní etí òkun ní Kafitori.

5. Ìbànújẹ́ ti dé bá Gasa, Aṣikeloni ti parun.Ẹ̀yin tí ẹ kù lára àwọn ọmọ Anakimu, ẹ óo ti fi ìbànújẹ́ ṣá ara yín lọ́gbẹ́ pẹ́ tó?

6. Ẹ̀yin ń bèèrè pé, ‘Ìwọ idà OLUWA,yóo ti pẹ́ tó kí o tó sinmi?Pada sinu àkọ̀ rẹ, máa sinmi kí o sì dúró jẹ́ẹ́.’

7. Ṣugbọn idà OLUWA ṣe lè dákẹ́ jẹ́ẹ́, nígbà tí Oluwa fún un ní iṣẹ́ láti ṣe?OLUWA ti pàṣẹ fún un láti kọlu Aṣikeloni, ati àwọn ìlú etí òkun.”