orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14
  15. 15
  16. 16
  17. 17
  18. 18
  19. 19
  20. 20
  21. 21
  22. 22
  23. 23
  24. 24
  25. 25
  26. 26
  27. 27
  28. 28
  29. 29
  30. 30
  31. 31
  32. 32
  33. 33
  34. 34
  35. 35
  36. 36
  37. 37
  38. 38
  39. 39
  40. 40
  41. 41
  42. 42
  43. 43
  44. 44
  45. 45
  46. 46
  47. 47
  48. 48
  49. 49
  50. 50
  51. 51
  52. 52

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremaya 21 BIBELI MIMỌ (BM)

Àsọtẹ́lẹ̀ nípa Ìṣubú Jerusalẹmu

1. Ọ̀rọ̀ tí Jeremaya gbọ́ lẹ́nu OLUWA nìyí nígbà tí ọba Sedekaya rán Paṣuri, ọmọ Malikaya, ati alufaa Sefanaya, ọmọ Maaseaya, sí i;

2. tí ọba Sedekaya ní, “Ẹ sọ fún Jeremaya pé kí ó bá wa ṣe ìwádìí lọ́dọ̀ OLUWA nípa Nebukadinesari, ọba Babiloni, tí ó gbógun tì wá; bóyá OLUWA yóo ṣe iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ fún wa, kí Nebukadinesari kó àwọn ọmọ ogun rẹ̀ kúrò ní ilẹ̀ wa.”

3. Jeremaya sọ fun awọn tí wọn rán sí i,

4. kí wọ́n sọ fún Sedekaya pé OLUWA Ọlọrun Israẹli ní, “N óo gba àwọn ohun ìjà tí ó wà lọ́wọ́ yín, tí ẹ fi ń bá ọba Babiloni ati àwọn ará Kalidea tí wọn gbógun tì yín lẹ́yìn odi jà, n óo dá wọn pada sí ààrin ìlú, n óo sì dojú wọn kọ yín.

5. Èmi fúnra mi ni n óo ba yín jà. Ipá ati agbára, pẹlu ibinu ńlá, ati ìrúnú gbígbóná ni n óo fi ba yín jà.

6. N óo fi àjàkálẹ̀ àrùn ńlá kọlu àwọn ará ìlú yìí, ati eniyan ati ẹranko ni yóo sì kú.

7. Lẹ́yìn náà n óo mú Sedekaya ọba Juda, ati àwọn ìjòyè rẹ̀, ati àwọn tí àjàkálẹ̀ àrùn, ogun, ati ìyàn, bá pa kù ní ìlú yìí, n óo fi wọ́n lé Nebukadinesari, ọba Babiloni lọ́wọ́, òun ati àwọn ọ̀tá tí ń wá ọ̀nà láti pa wọ́n. Ọba Babiloni yóo fi idà pa wọ́n, kò ní ṣàánú wọn, kò sì ní dá ẹnikẹ́ni sí.”

8. OLUWA ní, “Sọ fún àwọn eniyan yìí pé èmi OLUWA ni mo la ọ̀nà meji níwájú wọn: ọ̀nà ìyè ati ọ̀nà ikú.

9. Ogun, ìyàn ati àjàkálẹ̀ àrùn yóo pa ẹni tí ó bá dúró sinu ìlú yìí; ṣugbọn ẹni tí ó bá jáde tí ó sì fa ara rẹ̀ fún àwọn ará Kalidea, tí ó gbé ogun tì yín, yóo yè, yóo dàbí ẹni tó ja àjàbọ́.

10. Nítorí pé mo ti dójú lé ìlú yìí láti ṣe ní ibi, kì í ṣe fún rere. Ìlú yìí yóo bọ́ sọ́wọ́ ọba Babiloni, yóo sì dá iná sun ún, èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”

Ìdájọ́ lórí Ìdílé Ọba Juda

11. OLUWA ní kí n sọ fún ìdílé ọba Juda pé òun OLUWA ní,

12. “Ẹ̀yin ará ilé Dafidi!Ẹ máa dá ẹjọ́ ẹ̀tọ́ ní òwúrọ̀,ẹ máa gba ẹni tí a jà lólè lọ́wọ́ aninilára,kí ibinu èmi OLUWA má baà ru jáde, nítorí iṣẹ́ ibi yín,kí ó sì máa jó bíi iná,láìsí ẹni tí yóo lè pa á.”

13. OLUWA ní,“Ẹ wò ó, mo dojú ìjà kọ yín,ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gbé àfonífojì,tí ó dàbí àpáta tí ó yọ sókè ju pẹ̀tẹ́lẹ̀ lọ,ẹ̀yin tí ẹ̀ ń wí pé,‘Ta ló lè dojú ìjà kọ wá?Àbí ta ló lè wọ inú odi ìlú wa?’

14. N óo jẹ yín níyà gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ọwọ́ yín;èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.N óo dáná sun igbó yín,yóo sì jó gbogbo ohun tí ó wà ní agbègbè yín ní àjórun.”